Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 12:15-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Wọnyi li awọn ti o gòke odò Jordani li oṣù ekini, nigbati o kún bò gbogbo bèbe rẹ̀; nwọn si le gbogbo awọn ti o wà li afonifoji ninu ila-õrùn, ati niha iwọ-õrùn.

16. Ninu awọn ọmọ Benjamini ati Juda si tọ Dafidi wá lori òke.

17. Dafidi si jade lọ ipade wọn, o si dahun o si wi fun wọn pe, Bi o ba ṣepe ẹnyin tọ̀ mi wá li alafia lati ràn mi lọwọ, ọkàn mi yio ṣọkan pẹlu nyin: ṣugbọn bi o ba ṣepe ẹnyin wá lati fi mi hàn fun awọn ọta mi, nigbati ẹbi kò si lọwọ mi, ki Ọlọrun awọn baba wa ki o wò o, ki o si ṣe idajọ.

18. Nigbana ni ẹmi bà lé Amasai, ti iṣe olori awọn ọgbọn na, wipe, Tirẹ li awa, Dafidi, tirẹ li a si nṣe, iwọ ọmọ Jesse: alafia! alafia ni fun ọ! alafia si ni fun awọn oluranlọwọ rẹ; nitori Ọlọrun rẹ ni nràn ọ lọwọ. Dafidi si gbà wọn, o si fi wọn jẹ olori ẹgbẹ-ogun.

19. Ninu ẹyà Manasse si ya si ọdọ Dafidi, nigbati o ba awọn ara Filistia wá lati ba Saulu jagun, ṣugbọn nwọn kò ràn wọn lọwọ: nitori awọn olori awọn ara Filistia, nigbati nwọn gbero, rán a lọ wipe, Ti on ti ori wa ni on o fi pada lọ si ọdọ Saulu oluwa rẹ̀.

20. Bi on ti lọ si Siklagi, ninu awọn ẹya Manasse ya si ọdọ rẹ̀, Adna, ati Josabadi, Jediaeli, ati Mikaeli, ati Josabadi ati Elihu, ati Sittai, awọn olori ẹgbẹgbẹrun ti iṣe ti Manasse.

21. Nwọn si ràn Dafidi lọwọ si ẹgbẹ ogun na; nitori gbogbo wọn ni akọni enia, nwọn si jẹ olori ninu awọn ọmọ-ogun.

22. Nitori li akokò na li ojojumọ ni nwọn ntọ Dafidi wá lati ran a lọwọ, titi o fi di ogun nla, gẹgẹ bi ogun Ọlọrun.

23. Eyi ni iye awọn enia na ti o hamọra tan fun ogun, ti nwọn si tọ̀ Dafidi wá si Hebroni, lati pa ijọba Saulu da si ọdọ rẹ̀ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.

24. Awọn ọmọ Juda ti ngbe asa ati ọ̀kọ, jẹ ẹgbãta enia o le ẹgbẹrin, ti o hamọra tan fun ogun.

25. Ninu awọn ọmọ Simeoni, akọni enia fun ogun ẹ̃dẹgbarin o le ọgọrun.

26. Ninu awọn ọmọ Lefi, ẹgbãji o le ẹgbẹta.

27. Jehoiada olori fun Aaroni, ẹgbẹ̃dogun enia o le ẽdẹgbẹrin si wà pẹlu rẹ̀.

28. Ati Sadoku, akọni ọdọmọkunrin, ati ninu ile baba rẹ̀ olori mejilelogun.

29. Ati ninu awọn ọmọ Benjamini, awọn arakunrin Saulu ẹgbẹ̃dogun: nitori titi di isisiyi, ọ̀pọlọpọ ninu wọn li o ti ntọju iṣọ ile Saulu.

30. Ati ninu awọn ọmọ Efraimu ẹgbãwa o le ẹgbẹrin, akọni ọkunrin, enia olorukọ ni nwọn ni ile baba wọn.

31. Ati àbọ ẹ̀ya Manasse ẹgbãsan, ti a yan nipa orukọ, lati lọ fi Dafidi jẹ ọba.

Ka pipe ipin 1. Kro 12