Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 9:9-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Nwọn o si dahùn wipe, Nitoriti nwọn kọ̀ Oluwa Ọlọrun wọn silẹ, ẹniti o mu awọn baba wọn jade ti ilẹ Egipti wá, nwọn gbá awọn ọlọrun miran mú, nwọn si bọ wọn, nwọn si sìn wọn: nitorina ni Oluwa ṣe mu gbogbo ibi yi wá sori wọn.

10. O si ṣe lẹhin ogún ọdun, nigbati Solomoni ti kọ́ ile mejeji tan, ile Oluwa, ati ile ọba.

11. Hiramu, ọba Tire ti ba Solomoni wá igi kedari ati igi firi, ati wura gẹgẹ bi gbogbo ifẹ rẹ̀, nigbana ni Solomoni ọba fun Hiramu ni ogún ilu ni ilẹ Galili.

12. Hiramu si jade lati Tire wá lati wò ilu ti Solomoni fi fun u: nwọn kò si wù u.

13. On si wipe, Ilu kini wọnyi ti iwọ fi fun mi, arakunrin mi? O si pè wọn ni ilẹ Kabulu titi fi di oni yi.

14. Hiramu si fi ọgọta talenti wura ranṣẹ si ọba.

15. Idi awọn asìnru ti Solomoni kojọ ni eyi; lati kọ́ ile Oluwa, ati ile on tikararẹ̀, ati Millo, ati odi Jerusalemu, ati Hasori ati Megiddo, ati Geseri.

16. Farao, ọba Egipti ti goke lọ, o si ti kó Geseri, o si ti fi iná sun u, o si ti pa awọn ara Kenaani ti ngbe ilu na, o si fi ta ọmọbinrin rẹ̀, aya Solomoni li ọrẹ.

17. Solomoni si kọ́ Geseri, ati Bethoroni-isalẹ.

18. Ati Baalati, ati Tadmori ni aginju, ni ilẹ na.

19. Ati gbogbo ilu iṣura ti Solomoni ni, ati ilu kẹkẹ́ rẹ̀, ati ilu fun awọn ẹlẹsin rẹ̀, ati eyiti Solomoni nfẹ lati kọ́ ni Jerusalemu, ati ni Lebanoni, ati ni gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀.

20. Gbogbo enia ti o kù ninu awọn ara Amori, ara Hitti, Perisi, Hifi ati Jebusi, ti kì iṣe ti inu awọn ọmọ Israeli.

21. Awọn ọmọ wọn ti o kù lẹhin wọn ni ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli kò le parun tũtu, awọn ni Solomoni bù iṣẹ-iru fun titi di oni yi.

22. Ṣugbọn ninu awọn ọmọ Israeli, Solomoni kò fi ṣe ẹrú, ṣugbọn nwọn jẹ awọn ologun ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀, ati awọn balogun rẹ̀, ati awọn olori kẹkẹ́ rẹ̀ ati ti awọn ẹlẹsin rẹ̀.

23. Awọn wọnyi ni awọn olori olutọju ti mbẹ lori iṣẹ Solomoni, ãdọta-dilẹgbẹta, ti nṣe akoso lori awọn enia ti nṣe iṣẹ na.

24. Ṣugbọn ọmọbinrin Farao goke lati ilu Dafidi wá si ile rẹ̀, ti Solomoni kọ́ fun u: nigbana ni o kọ́ Millo.

25. Ati nigba mẹta li ọdun ni Solomoni iru ẹbọ ọrẹ-sisun, ati ẹbọ-ọpẹ lori pẹpẹ ti o tẹ́ fun Oluwa, o si sun turari lori eyi ti mbẹ niwaju Oluwa. Bẹ̃li o pari ile na.

26. Solomoni ọba si sẹ ọ̀wọ-ọkọ̀ ni Esioni-Geberi, ti mbẹ li ẹba Eloti, leti Okun-pupa ni ilẹ Edomu.

27. Hiramu si rán awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn atukọ ti o ni ìmọ okun, pẹlu awọn iranṣẹ Solomoni ninu ọ̀wọ-ọkọ̀ na.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 9