Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 7:37-51 Yorùbá Bibeli (YCE)

37. Gẹgẹ bayi li o si ṣe awọn ijoko mẹwẹwa: gbogbo wọn li o si ni didà kanna, iwọ̀n kanna ati titobi kanna.

38. O si ṣe agbada idẹ mẹwa: agbada kan gbà to òji iwọn Bati: agbada kọ̃kan si jẹ igbọnwọ mẹrin: lori ọkọ̃kan ijoko mẹwẹwa na ni agbada kọ̃kan wà.

39. O si fi ijoko marun si apa ọtún ile na, ati marun si apa òsi ile na: o si gbe agbada-nla ka apa ọ̀tún ile na, si apa ila-õrun si idojukọ gusu:

40. Hiramu si ṣe ikoko ati ọkọ́, ati awo-koto. Bẹ̃ni Hiramu si pari gbogbo iṣẹ ti o ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba:

41. Ọwọ̀n meji, ati ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n meji; ati iṣẹ àwọ̀n meji lati bò ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n;

42. Ati irinwo pomegranate fun iṣẹ àwọ̀n meji, ọ̀wọ́ meji pomegranate fun iṣẹ àwọ̀n kan, lati bò awọn ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n;

43. Ati ijoko mẹwa, ati agbada mẹwa lori awọn ijoko na.

44. Agbada nla kan, ati malu mejila labẹ agbada nla.

45. Ati ikoko, ati ọkọ́, ati awo-koto; ati gbogbo ohun-elo wọnyi ti Hiramu ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba, jẹ ti idẹ didan.

46. Ni pẹtẹlẹ Jordani ni ọba dà wọn, ni ilẹ amọ̀ ti mbẹ lagbedemeji Sukkoti on Sartani.

47. Solomoni si jọwọ gbogbo ohun-elo na silẹ li alaiwọ̀n, nitori ti nwọn papọju: bẹ̃ni a kò si mọ̀ iwọ̀n idẹ na.

48. Solomoni si ṣe gbogbo ohun-elo ti iṣe ti ile Oluwa: pẹpẹ wura, ati tabili wura, lori eyi ti akara ifihan gbe wà.

49. Ati ọpa fitila wura daradara, marun li apa ọtún ati marun li apa òsi, niwaju ibi mimọ́-julọ, pẹlu itanna eweko, ati fitila, ati ẹ̀mú wura.

50. Ati ọpọ́n, ati alumagaji-fitila, ati awo-koto, ati ṣibi, ati awo turari ti wura daradara; ati agbekọ wura, fun ilẹkun inu ile, ibi mimọ́-julọ, ati fun ilẹkun ile na, ani ti tempili.

51. Bẹ̃ni gbogbo iṣẹ ti Solomoni ọba ṣe fun ile Oluwa pari. Solomoni si mu gbogbo nkan ti Dafidi baba rẹ̀ ti yà si mimọ́ wá; fadaka, ati wura, ati ohun-elo, o si fi wọn sinu iṣura ile Oluwa.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 7