Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 5:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. HIRAMU, ọba Tire, si rán awọn iranṣẹ rẹ̀ si Solomoni; nitoriti o ti gbọ́ pe, a ti fi ororo yàn a li ọba ni ipò baba rẹ̀: nitori Hiramu ti fẹràn Dafidi li ọjọ rẹ̀ gbogbo.

2. Solomoni si ranṣẹ si Hiramu wipe,

3. Iwọ mọ̀ bi Dafidi, baba mi, kò ti le kọ́ ile fun orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀ nitori ogun ti o wà yi i ka kiri, titi Oluwa fi fi wọn sabẹ atẹlẹsẹ rẹ̀.

4. Ṣugbọn nisisiyi Oluwa Ọlọrun mi ti fun mi ni isimi niha gbogbo, bẹ̃ni kò si si ọta tabi ibi kan ti o ṣẹ̀.

5. Si kiye si i, mo gbèro lati kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa Ọlọrun mi, gẹgẹ bi Oluwa ti sọ fun Dafidi, baba mi pe, Ọmọ rẹ, ti emi o gbe kà ori itẹ́ rẹ ni ipò rẹ, on ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi.

6. Njẹ nisisiyi, paṣẹ ki nwọn ki o ke igi kedari fun mi lati Lebanoni wá, awọn ọmọ ọdọ mi yio si wà pẹlu awọn ọmọ ọdọ rẹ, iwọ ni emi o si sanwo ọyà awọn ọmọ ọdọ rẹ fun, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti iwọ o wi: nitoriti iwọ mọ̀ pe, kò si ẹnikan ninu wa ti o mọ̀ bi a ti ike igi bi awọn ara Sidoni.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 5