Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 4:23-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Malu mẹwa ti o sanra, ati ogún malu lati inu papa wá, ati ọgọrun agutan, laika agbọ̀nrin, ati egbin, ati ogbúgbu, ati ẹiyẹ ti o sanra.

24. Nitori on li o ṣe alaṣẹ lori gbogbo agbègbe ni iha ihin odò, lati Tifsa titi de Gasa, lori gbogbo awọn ọba ni iha ihin odò: o si ni alafia ni iha gbogbo yi i kakiri.

25. Juda ati Israeli ngbe li alafia, olukuluku labẹ àjara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ́ rẹ̀, lati Dani titi de Beerṣeba, ni gbogbo ọjọ Solomoni.

26. Solomoni si ni ẹgbãji ile-ẹṣin fun kẹkẹ́ rẹ̀, ati ẹgbãfa ẹlẹṣin.

27. Awọn ijoye na si pesè onjẹ fun Solomoni ọba, ati fun gbogbo awọn ti o wá sibi tabili Solomoni ọba, olukuluku li oṣu tirẹ̀: nwọn kò fẹ nkankan kù.

28. Ọkà barle pẹlu, ati koriko fun ẹṣin ati fun ẹṣin sisare ni nwọn mu wá sibiti o gbe wà, olukuluku gẹgẹ bi ilana tirẹ̀.

29. Ọlọrun si fun Solomoni li ọgbọ́n ati oye li ọ̀pọlọpọ, ati oye gbigboro, gẹgẹ bi iyanrin ti o wà leti okun.

30. Ọgbọ́n Solomoni si bori ọgbọ́n gbogbo awọn ọmọ ila-õrun, ati gbogbo ọgbọ́n Egipti.

31. On si gbọ́n jù gbogbo enia; jù Etani, ara Esra, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara, awọn ọmọ Maholi: okiki rẹ̀ si kàn ni gbogbo orilẹ-ède yíka.

32. O si pa ẹgbẹdọgbọn owe: orin rẹ̀ si jẹ ẹgbẹrun o le marun.

33. O si sọ̀rọ ti igi, lati kedari ti mbẹ ni Lebanoni, ani titi de hissopu ti nhu lara ogiri: o si sọ̀ ti ẹranko pẹlu, ati ti ẹiyẹ, ati ohun ti nrako, ati ti ẹja.

34. Ẹni pupọ si wá lati gbogbo orilẹ-ède lati gbọ́ ọgbọ́n Solomoni; ani lati ọdọ gbogbo awọn ọba aiye, ti o gburo ọgbọ́n rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 4