Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 3:2-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Kiki pe, awọn enia nrubọ ni ibi giga, nitori a kò ti ikọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, titi di ọjọ wọnnì.

3. Solomoni si fẹ Oluwa, o si nrin nipa aṣẹ Dafidi baba rẹ̀: ṣugbọn kiki pe, o nrubọ, o si nfi turari jona ni ibi-giga.

4. Ọba si lọ si Gibeoni lati rubọ nibẹ; nitori ibẹ ni ibi-giga nlanla: ẹgbẹrun ọrẹ ẹbọ-sisun ni Solomoni ru lori pẹpẹ na.

5. Ni Gibeoni ni Oluwa fi ara rẹ̀ hàn Solomoni loju alá li oru: Ọlọrun si wipe, Bère ohun ti emi o fi fun ọ.

6. Solomoni si wipe, Iwọ ti ṣe ore nla fun iranṣẹ rẹ, Dafidi baba mi, gẹgẹ bi o ti rin niwaju rẹ li otitọ ati li ododo, ati ni iduro-ṣinṣin ọkàn pẹlu rẹ, iwọ si pa ore nla yi mọ fun u lati fun u li ọmọkunrin ti o joko lori itẹ rẹ̀, gẹgẹ bi o ti ri loni yi.

7. Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun mi, iwọ ti fi iranṣẹ rẹ jẹ ọba ni ipo Dafidi, baba mi: ati emi, ọmọ kekere ni mi, emi kò si mọ̀ jijade ati wiwọle.

8. Iranṣẹ rẹ si mbẹ lãrin awọn enia rẹ ti iwọ ti yàn, enia pupọ, ti a kò le moye, ti a kò si lè kà fun ọ̀pọlọpọ.

9. Nitorina, fi ọkàn imoye fun iranṣẹ rẹ lati ṣe idajọ awọn enia rẹ, lati mọ̀ iyatọ rere ati buburu; nitori tali o le ṣe idajọ awọn enia rẹ yi ti o pọ̀ to yi?

10. Ọ̀rọ na si dara loju Oluwa, nitoriti Solomoni bère nkan yi.

11. Ọlọrun si wi fun u pe, Nitoriti iwọ bère nkan yi, ti iwọ kò si bère ẹmi gigun fun ara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò bère ọlá fun ara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò bère ẹmi awọn ọta rẹ; ṣugbọn iwọ bère oye fun ara rẹ lati mọ̀ ẹjọ-idá;

12. Wò o, emi ti ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, wò o, emi fun ọ ni ọkàn ọgbọ́n ati imoye; tobẹ̃ ti kò ti isi ẹnikan ti o dabi rẹ ṣãju rẹ, bẹ̃ni lẹhin rẹ ẹnikan kì yio dide ti yio dabi rẹ.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 3