Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 3:13-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ati eyiti iwọ kò bere, emi o fun ọ pẹlu ati ọrọ̀ ati ọlá: tobẹ̃ ti kì yio si ọkan ninu awọn ọba ti yio dabi rẹ.

14. Bi iwọ o ba si rìn ni ọ̀na mi lati pa aṣẹ ati ofin mi mọ, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ ti rìn, emi o si sún ọjọ rẹ siwaju.

15. Solomoni si jí; si wò o, alá ni. On si wá si Jerusalemu, o si duro niwaju apoti majẹmu Oluwa, o si rubọ ọrẹ sisun, o si ru ẹbọ-alafia, o si se àse fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀.

16. Nigbana ni obinrin meji, ti iṣe àgbere, wá sọdọ ọba nwọn si duro niwaju rẹ̀.

17. Ọkan ninu wọn si wipe, Jọwọ, oluwa mi, emi ati obinrin yi ngbe ile kan; emi si bi ọmọ ni ile pẹlu rẹ̀.

18. O si ṣe ni ọjọ kẹta lẹhin igbati mo bimọ tan, obinrin yi si bimọ pẹlu: awa si jumọ ngbé pọ: kò si si alejo pẹlu wa ni ile bikoṣe awa mejeji ni ile.

19. Ọmọ obinrin yi si kú li oru; nitoriti o sun le e.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 3