Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 21:14-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nigbana ni nwọn ranṣẹ si Jesebeli wipe, A sọ Naboti li okuta, o si kú.

15. O si ṣe, nigbati Jesebeli gbọ́ pe, a sọ Naboti li okuta, o si kú, Jesebeli sọ fun Ahabu pe, Dide! ki o si jogun ọgba-ajara Naboti, ara Jesreeli, ti o kọ̀ lati fi fun ọ fun owo; nitori Naboti kò si lãye ṣugbọn o kú.

16. O si ṣe, nigbati Ahabu gbọ́ pe, Naboti kú, ni Ahabu dide lati sọkalẹ lọ si ọgba-ajara Naboti, ara Jesreeli lati jogun rẹ̀.

17. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Elijah, ara Tiṣbi wá wipe,

18. Dide, sọkalẹ, lọ ipade Ahabu, ọba Israeli, ti o wà ni Samaria: wò o, o wà ni ọgba-ajara Naboti, nibiti o sọkalẹ lọ lati jogun rẹ̀.

19. Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi: Iwọ ti pa, iwọ si ti jogun pẹlu? Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi pe, Ni ibi ti ajá gbe lá ẹ̀jẹ Naboti, ni awọn ajá yio lá ẹ̀jẹ rẹ, ani tirẹ.

20. Ahabu si wi fun Elijah pe, Iwọ ri mi, Iwọ ọta mi? O si dahùn wipe, Emi ri ọ; nitoriti iwọ ti tà ara rẹ lati ṣiṣẹ buburu niwaju Oluwa.

21. Kiyesi i, Emi o mu ibi wá si ori rẹ, emi o si mu iran rẹ kuro, emi o si ke kuro lọdọ Ahabu, gbogbo ọmọde ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ, ati omnira ni Israeli.

22. Emi o si ṣe ile rẹ bi ile Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati bi ile Baaṣa, ọmọ Ahijah, nitori imunibinu ti iwọ ti mu mi binu, ti iwọ si mu ki Israeli ki o dẹ̀ṣẹ.

23. Ati niti Jesebeli pẹlu Oluwa sọ wipe, Awọn ajá yio jẹ Jesebeli ninu yàra Jesreeli.

24. Ẹni Ahabu ti o kú ni ilu, ni awọn ajá o jẹ; ati ẹniti o kú ni igbẹ ni awọn ẹiyẹ oju-ọrun o jẹ.

25. Ṣugbọn kò si ẹnikan bi Ahabu ti o tà ara rẹ̀ lati ṣiṣẹ buburu niwaju Oluwa, ẹniti Jesebeli aya rẹ̀ ntì.

26. O si ṣe ohun irira gidigidi ni titọ̀ oriṣa lẹhin, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti awọn ara Amori ti ṣe, ti Oluwa ti le jade niwaju awọn ọmọ Israeli.

27. O si ṣe, nigbati Ahabu gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ si ara rẹ̀, o si gbàwẹ, o si dubulẹ ninu aṣọ ọ̀fọ, o si nlọ jẹ́.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 21