Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 20:8-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ati gbogbo awọn àgba ati gbogbo awọn enia wi fun u pe, Máṣe fi eti si tirẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe gbà fun u.

9. Nitorina li o sọ fun awọn onṣẹ Benhadadi pe, Wi fun oluwa mi ọba pe, ohun gbogbo ti iwọ ranṣẹ fun, sọdọ iranṣẹ rẹ latetekọṣe li emi o ṣe: ṣugbọn nkan yi li emi kò le ṣe. Awọn onṣẹ na pada lọ, nwọn si tun mu èsi fun u wá.

10. Benhadadi si ranṣẹ si i, o si wipe, Ki awọn oriṣa ki o ṣe bẹ̃ si mi, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu bi ẽkuru Samaria yio to fun ikunwọ fun gbogbo enia ti ntẹle mi.

11. Ọba Israeli si dahùn, o si wipe, Wi fun u pe, Má jẹ ki ẹniti nhamọra, ki o halẹ bi ẹniti mbọ́ ọ silẹ,

12. O si ṣe, nigbati Benhadadi gbọ́ ọ̀rọ yi, bi o ti nmuti, on ati awọn ọba ninu agọ, li o sọ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ tẹ́gun si ilu na.

13. Si kiyesi i, woli kan tọ̀ Ahabu, ọba Israeli wá, wipe, Bayi li Oluwa wi, Iwọ ri gbogbo ọ̀pọlọpọ yi? kiyesi i, emi o fi wọn le ọ lọwọ loni; iwọ o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.

14. Ahabu wipe, Nipa tani? On si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nipa awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko. Nigbana li o wipe, Tani yio wé ogun na? On si dahùn pe: Iwọ.

15. Nigbana li o kà awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko, nwọn si jẹ igba o le mejilelọgbọn: lẹhin wọn li o si kà gbogbo awọn enia, ani gbogbo awọn ọmọ Israeli jẹ ẹdẹgbarin.

16. Nwọn si jade lọ li ọjọ-kanri. Ṣugbọn Benhadadi mu amupara ninu agọ, on, ati awọn ọba, awọn ọba mejilelọgbọn ti nràn a lọwọ.

17. Awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko tètekọ jade lọ: Benhadadi si ranṣẹ jade, nwọn si sọ fun u wipe, awọn ọkunrin nti Samaria jade wá.

18. On si wipe, Bi nwọn ba bá ti alafia jade, ẹ mu wọn lãye; tabi bi ti ogun ni nwọn ba bá jade, ẹ mu wọn lãye.

19. Bẹ̃ni awọn ipẹrẹ̀ wọnyi ti awọn ijoye igberiko jade ti ilu wá, ati ogun ti o tẹle wọn.

20. Nwọn si pa, olukuluku ọkunrin kọkan; awọn ara Siria sa; Israeli si lepa wọn: Benhadadi, ọba Siria si sala lori ẹṣin pẹlu awọn ẹlẹṣin.

21. Ọba Israeli si jade lọ, o si kọlu awọn ẹṣin ati kẹkẹ́, o pa awọn ara Siria li ọ̀pọlọpọ.

22. Woli na si wá sọdọ ọba Israeli, o si wi fun u pe, Lọ, mu ara rẹ giri, ki o si mọ̀, ki o si wò ohun ti iwọ nṣe: nitori li amọdun, ọba Siria yio goke tọ̀ ọ wá.

23. Awọn iranṣẹ ọba Siria si wi fun u pe, ọlọrun wọn, ọlọrun oke ni; nitorina ni nwọn ṣe li agbara jù wa lọ; ṣugbọn jẹ ki a ba wọn jà ni pẹtẹlẹ, awa o si li agbara jù wọn lọ nitõtọ.

24. Nkan yi ni ki o si ṣe, mu awọn ọba kuro, olukuluku kuro ni ipò rẹ̀, ki o si fi olori-ogun si ipò wọn.

25. Ki o si kà iye ogun fun ara rẹ gẹgẹ bi ogun ti o ti fọ́, ẹṣin fun ẹṣin, ati kẹkẹ́ fun kẹkẹ́: awa o si ba wọn jà ni pẹ̀tẹlẹ, nitõtọ awa o li agbara jù wọn lọ. O si fi eti si ohùn wọn, o si ṣe bẹ̃.

26. O si ṣe li amọdun, ni Benhadadi kà iye awọn ara Siria, nwọn si goke lọ si Afeki, lati bá Israeli jagun.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 20