Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 20:35-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

35. Ọkunrin kan ninu awọn ọmọ awọn woli si wi fun ẹnikeji rẹ̀ nipa ọ̀rọ Oluwa pe, Jọ̃, lù mi. Ọkunrin na si kọ̀ lati lù u.

36. Nigbana li o wi pe, Nitoriti iwọ kò gbà ohùn Oluwa gbọ́, kiyesi i, bi iwọ ba ti ọdọ mi kuro, kiniun yio pa ọ. Bi o si ti jade lọ lọdọ rẹ̀, kiniun kan ri i o si pa a.

37. Nigbana li o si ri ọkunrin miran, o si wipe, Jọ̃, lù mi. Ọkunrin na si lù u, ni lilu ti o lù u, o pa a lara.

38. Woli na si lọ, o si duro de ọba loju ọ̀na, o pa ara rẹ̀ da, ni fifi ẽru ba oju.

39. Bi ọba si ti nkọja lọ, o ke si ọba o si wipe, iranṣẹ rẹ jade wọ arin ogun lọ; si kiyesi i, ọkunrin kan yà sapakan, o si mu ọkunrin kan fun mi wá o si wipe: Pa ọkunrin yi mọ; bi a ba fẹ ẹ kù, nigbana ni ẹmi rẹ yio lọ fun ẹmi rẹ̀, bi bẹ̃ kọ, iwọ o san talenti fadaka kan.

40. Bi iranṣẹ rẹ si ti ni iṣe nihin ati lọhun, a fẹ ẹ kù. Ọba Israeli si wi fun u pe, Bẹ̃ni idajọ rẹ yio ri: iwọ tikararẹ ti dá a.

41. O si yara, o si mu ẹ̃ru kuro li oju rẹ̀; ọba Israeli si ri i daju pe, ọkan ninu awọn woli ni on iṣe.

42. O si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, nitoriti iwọ jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ, ọkunrin ti emi ti yàn si iparun patapata, ẹmi rẹ yio lọ fun ẹmi rẹ̀, ati enia rẹ fun enia rẹ̀.

43. Ọba Israeli si lọ si ile rẹ̀, o wugbọ, inu rẹ̀ si bajẹ o si wá si Samaria.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 20