Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 2:16-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Nisisiyi, ibere kan ni mo wá bere lọwọ rẹ, máṣe dù mi: O si wi fun u pe, Mã wi.

17. O si wi pe, Mo bẹ ọ, sọ fun Solomoni ọba (nitori kì yio dù ọ,) ki o fun mi ni Abiṣagi, ara Ṣunemu li aya.

18. Batṣeba si wipe, o dara; emi o ba ọba sọrọ nitori rẹ.

19. Batṣeba si tọ Solomoni ọba lọ, lati sọ fun u nitori Adonijah. Ọba si dide lati pade rẹ̀, o si tẹ ara rẹ̀ ba fun u, o si joko lori itẹ́ rẹ̀ o si tẹ́ itẹ fun iya ọba, on si joko lọwọ ọtun rẹ̀.

20. On si wipe, Ibere kekere kan li emi ni ibere lọwọ rẹ; máṣe dù mi. On si wipe, mã tọrọ, iya mi; nitoriti emi kì yio dù ọ.

21. On si wipe, jẹ ki a fi Abiṣagi, ara Ṣunemu, fun Adonijah, arakunrin rẹ, li aya.

22. Solomoni ọba si dahùn, o si wi fun iya rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi mbere Abiṣagi, ara Ṣunemu, fun Adonijah, kuku bere ijọba fun u pẹlu; nitori ẹgbọ́n mi ni iṣe; fun on pãpa, ati fun Abiatari, alufa, ati fun Joabu, ọmọ Seruiah.

23. Solomoni, ọba si fi Oluwa bura pe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o ṣe si mi, ati jubẹ pẹlu, nitori Adonijah sọ̀rọ yi si ẹmi ara rẹ̀.

24. Ati nisisiyi bi Oluwa ti wà, ti o ti fi idi mi mulẹ̀, ti o si mu mi joko lori itẹ́ baba mi, ti o si ti kọ́ ile fun mi, gẹgẹ bi o ti wi, loni ni a o pa Adonijah.

25. Solomoni, ọba si rán Benaiah, ọmọ Jehoiada, o si kọlu u, o si kú.

26. Ati fun Abiatari, alufa, ọba wipe, Lọ si Anatoti, si oko rẹ; nitori iwọ yẹ si ikú: ṣugbọn loni emi kì yio pa ọ, nitori iwọ li o ti ngbe apoti Oluwa Ọlọrun niwaju Dafidi baba mi, ati nitori iwọ ti jẹ ninu gbogbo iyà ti baba mi ti jẹ.

27. Solomoni si le Abiatari kuro ninu iṣẹ alufa Oluwa; ki o le mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ, ti o ti sọ nipa ile Eli ni Ṣilo.

28. Ihin si de ọdọ Joabu: nitori Joabu ti tọ̀ Adonijah lẹhin, ṣugbọn kò tọ̀ Absalomu lẹhin: Joabu si sá sinu agọ Oluwa, o si di iwo pẹpẹ mu.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 2