On si wipe, Iwọ mọ̀ pe, ijọba na ti emi ni ri, ati pe, gbogbo Israeli li o fi oju wọn si mi lara pe, emi ni o jọba: ṣugbọn ijọba na si yí, o si di ti arakunrin mi; nitori tirẹ̀ ni lati ọwọ́ Oluwa wá.