Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 18:39-46 Yorùbá Bibeli (YCE)

39. Nigbati gbogbo awọn enia ri i, nwọn da oju wọn bolẹ: nwọn si wipe, Oluwa, on li Ọlọrun; Oluwa, on li Ọlọrun!

40. Elijah si wi fun wọn pe, Ẹ mu awọn woli Baali; máṣe jẹ ki ọkan ninu wọn ki o salà. Nwọn si mu wọn: Elijah si mu wọn sọkalẹ si odò Kiṣoni, o si pa wọn nibẹ.

41. Elijah si wi fun Ahabu pe, Goke lọ, jẹ, ki o si mu; nitori iró ọ̀pọlọpọ òjo mbẹ.

42. Bẹ̃ni Ahabu goke lọ lati jẹ ati lati mu. Elijah si gun ori oke Karmeli lọ; o si tẹriba o si fi oju rẹ̀ si agbedemeji ẽkun rẹ̀,

43. O si wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Goke lọ nisisiyi, ki o si wò iha okun. On si goke lọ, o si wò, o si wipe, Kò si nkan. O si wipe, Tun lọ nigba meje.

44. O si ṣe, ni igba keje, o si wipe, Kiyesi i, awọsanmọ kekere kan dide lati inu okun, gẹgẹ bi ọwọ́ enia. On si wipe, Goke lọ, wi fun Ahabu pe, Di kẹkẹ́ rẹ, ki o si sọkalẹ, ki òjo ki o má ba da ọ duro.

45. O si ṣe, nigba diẹ si i, ọrun si ṣu fun awọsanmọ on iji, òjo pupọ si rọ̀. Ahabu si gun kẹkẹ́, o si lọ si Jesreeli.

46. Ọwọ́ Oluwa si mbẹ lara Elijah: o si di amure ẹ̀gbẹ rẹ̀, o si sare niwaju Ahabu titi de Jesreeli.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 18