Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 18:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, lẹhin ọjọ pupọ, ọ̀rọ Oluwa tọ Elijah wá lọdun kẹta, wipe, Lọ, fi ara rẹ hàn Ahabu; emi o si rọ̀ òjo sori ilẹ.

2. Elijah si lọ ifi ara rẹ̀ han Ahabu. Iyan nla si mu ni Samaria.

3. Ahabu si pe Obadiah, ti iṣe olori ile rẹ̀. Njẹ Obadiah bẹ̀ru Oluwa gidigidi:

4. O si ṣe, nigbati Jesebeli ke awọn woli Oluwa kuro, ni Obadiah mu ọgọrun woli, o si fi wọn pamọ li aradọta ni iho okuta; o si fi àkara pẹlu omi bọ́ wọn.

5. Ahabu si wi fun Obadiah pe, Rin ilẹ lọ, si orisun omi gbogbo, ati si odò gbogbo: bọya awa le ri koriko lati gbà awọn ẹṣin ati awọn ibãka là, ki a má ba ṣòfo awọn ẹranko patapata.

6. Nwọn si pin ilẹ na lãrin ara wọn, lati là a ja: Ahabu gba ọ̀na kan lọ fun ara rẹ̀, Obadiah si gba ọ̀na miran lọ fun ara rẹ̀.

7. Nigbati Obadiah si wà li ọ̀na, kiyesi i, Elijah pade rẹ̀: nigbati o mọ̀ ọ, o si doju rẹ̀ bolẹ, o si wipe, Ṣé iwọ oluwa mi Elijah nìyí?

8. O si da a lohùn pe, Emi ni: lọ, sọ fun oluwa rẹ pe, Wò o, Elijah mbẹ nihin.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 18