Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 17:16-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Ikoko iyẹfun na kò ṣòfo, bẹ̃ni kólobo ororo na kò gbẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti ipa Elijah sọ.

17. O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni ọmọ obinrin na, iya ile na, ṣe aisàn; aisàn rẹ̀ na si le to bẹ̃, ti kò kù ẹmi ninu rẹ̀.

18. On si wi fun Elijah pe, Kili o ṣe mi ṣe ọ, Iwọ enia Ọlọrun? iwọ ha tọ̀ mi wá lati mu ẹ̀ṣẹ mi wá si iranti, ati lati pa mi li ọmọ?

19. On si wi fun u pe, Gbé ọmọ rẹ fun mi. Elijah si yọ ọ jade li aiya rẹ̀, o si gbé e lọ si iyara-òke ile nibiti on ngbe, o si tẹ́ ẹ si ori akete tirẹ̀.

20. O si kepe OLUWA, o si wipe, OLUWA Ọlọrun mi, iwọ ha mu ibi wá ba opó na pẹlu lọdọ ẹniti emi nṣe atipo, ni pipa ọmọ rẹ̀?

21. On si nà ara rẹ̀ lori ọmọde na li ẹrinmẹta, o si kepe Oluwa, o si wipe, Oluwa Ọlọrun mi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ẹmi ọmọde yi ki o tun padà wá sinu rẹ̀.

22. Oluwa si gbọ́ ohùn Elijah; ẹmi ọmọde na si tun padà wá sinu rẹ̀, o si sọji.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 17