Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 11:15-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. O si ṣe, nigbati Dafidi wà ni Edomu, ati ti Joabu olori-ogun goke lọ lati sìn awọn ti a pa, nigbati o pa gbogbo ọkunrin ni Edomu.

16. Nitori oṣù mẹfa ni Joabu fi joko nibẹ ati gbogbo Israeli, titi o fi ké gbogbo ọkunrin kuro ni Edomu:

17. Hadadi si sá, on ati awọn ara Edomu ninu awọn iranṣẹ baba rẹ̀ pẹlu rẹ̀, lati lọ si Egipti; ṣugbọn Hadadi wà li ọmọde.

18. Nwọn si dide kuro ni Midiani, nwọn si wá si Parani; nwọn si mu enia pẹlu wọn lati Parani wá: nwọn si wá si Egipti, sọdọ Farao ọba Egipti, o si fun u ni ile kan, o si yàn onjẹ fun u, o si fun u ni ilẹ.

19. Hadadi si ri oju-rere pupọ̀ niwaju Farao, o si fun u li arabinrin aya rẹ̀, li aya, arabinrin Tapenesi, ayaba.

20. Arabinrin Tapenesi si bi Genubati ọmọ rẹ̀ fun u, Tapenesi si já a li ẹnu ọmu ni ile Farao: Genubati si wà ni ile Farao lãrin awọn ọmọ Farao,

21. Nigbati Hadadi si gbọ́ ni Egipti pe, Dafidi sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, ati pe Joabu olori-ogun si kú, Hadadi si wi fun Farao pe, rán mi lọ, ki emi ki o le lọ si ilu mi.

22. Nigbana ni Farao wi fun u pe, ṣugbọn kini iwọ ṣe alaini lọdọ mi, si kiyesi i, iwọ nwá ọ̀na lati lọ si ilu rẹ? O si wipe: Kò si nkan: ṣugbọn sa jẹ ki emi ki o lọ.

23. Pẹlupẹlu Ọlọrun gbe ọta dide si i; ani Resoni, ọmọ Eliada, ti o ti sá kuro lọdọ Hadadeseri oluwa rẹ̀, ọba Soba:

24. On si ko enia jọ sọdọ ara rẹ̀, o si di olori-ogun ẹgbẹ́ kan, nigbati Dafidi fi pa wọn, nwọn si lọ si Damasku, nwọn ngbe ibẹ, nwọn si jọba ni Damasku.

25. On si ṣe ọta si Israeli ni gbogbo ọjọ Solomoni, lẹhin ibi ti Hadadi ṣe: Resoni si korira Israeli, o si jọba lori Siria.

26. Ati Jeroboamu, ọmọ Nebati, ara Efrati ti Sereda, iranṣẹ Solomoni, orukọ iya ẹniti ijẹ Serua, obinrin opó kan, on pẹlu gbe ọwọ soke si ọba.

27. Eyi si ni idi ohun ti o ṣe gbe ọwọ soke si ọba: Solomoni kọ́ Millo, o si di ẹya ilu Dafidi baba rẹ̀.

28. Ọkunrin na, Jeroboamu, ṣe alagbara akọni: nigbati Solomoni si ri ọdọmọkunrin na pe, oṣiṣẹ enia ni, o fi i ṣe olori gbogbo iṣẹ-iru ile Josefu.

29. O si ṣe li àkoko na, nigbati Jeroboamu jade kuro ni Jerusalemu, woli Ahijah ara Ṣilo ri i loju ọ̀na; o si wọ̀ agbáda titun; awọn meji pere li o si mbẹ ni oko:

30. Ahijah si gbà agbáda titun na ti o wà lara rẹ̀, o si fà a ya si ọ̀na mejila:

31. O si wi fun Jeroboamu pe, Iwọ mu ẹya mẹwa: nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, Wò o, emi o fa ijọba na ya kuro li ọwọ Solomoni, emi o si fi ẹya mẹwa fun ọ.

32. Ṣugbọn on o ni ẹya kan nitori Dafidi iranṣẹ mi, ati nitori Jerusalemu, ilu ti mo ti yàn ninu gbogbo ẹya Israeli:

33. Nitori ti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si mbọ Astoreti, oriṣa awọn ara Sidoni, ati Kemoṣi, oriṣa awọn ara Moabu, ati Milkomu, oriṣa awọn ọmọ Ammoni, nwọn kò si rin li ọ̀na mi, lati ṣe eyiti o tọ́ li oju mi, ati lati pa aṣẹ mi ati idajọ mi mọ́, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀.

34. Ṣugbọn emi kì yio gba gbogbo ijọba na lọwọ rẹ̀, ṣugbọn emi o ṣe e li ọmọ-alade ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, nitori Dafidi, iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn, nitori o ti pa ofin mi ati aṣẹ mi mọ́:

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 11