Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 1:42-53 Yorùbá Bibeli (YCE)

42. Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, Jonatani, ọmọ Abiatari, alufa de; Adonijah si wi fun u pe, Mã wolẹ̀; nitoripe alagbara ọkunrin ni iwọ, ati ẹniti nmu ihin-rere wá.

43. Jonatani si dahùn o si wi fun Adonijah pe, Lõtọ ni, oluwa wa, Dafidi ọba, fi Solomoni jọba.

44. Ọba si ti rán Sadoku alufa, ati Natani woli, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati awọn ara Kereti ati Peleti pẹlu rẹ̀, nwọn si ti mu u ki o gùn ibãka ọba.

45. Sadoku, alufa ati Natani, woli si ti fi ororo yàn a li ọba ni Gihoni: nwọn si fi ayọ̀ goke lati ibẹ wá, tobẹ̃ ti ilu si nho. Eyi ni ariwo ti ẹ ti gbọ́.

46. Solomoni si joko lori itẹ ijọba pẹlu.

47. Awọn iranṣẹ ọba si wá lati sure fun oluwa wa, Dafidi ọba, pe, Ki Ọlọrun ki o mu orukọ Solomoni ki o sàn jù orukọ rẹ lọ, ki o si ṣe itẹ rẹ̀ ki o pọ̀ jù itẹ rẹ lọ. Ọba si gbadura lori akete.

48. Ọba si wi bayi pẹlu, Olubukun li Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti o fun mi li ẹnikan ti o joko lori itẹ mi loni, oju mi si ri i.

49. Gbogbo awọn ti a pè, ti nwọn wà li ọdọ Adonijah si bẹ̀ru, nwọn si dide, nwọn si lọ olukuluku si ọ̀na rẹ̀.

50. Adonijah si bẹ̀ru Solomoni, o si dide, o si lọ, o si di iwo pẹpẹ mu.

51. Nwọn si wi fun Solomoni pe, Wò o, Adonijah bẹ̀ru Solomoni ọba: si kiyesi i, o di iwo pẹpẹ mu, o nwipe, Ki Solomoni ọba ki o bura fun mi loni pe, On kì yio fi idà pa iranṣẹ rẹ̀.

52. Solomoni si wipe, Bi o ba jẹ fi ara rẹ̀ si ọ̀wọ, irun ori rẹ̀ kan kì yio bọ́ silẹ: ṣugbọn bi a ba ri buburu lọwọ rẹ̀, on o kú.

53. Solomoni ọba si ranṣẹ, nwọn mu u sọkalẹ lori pẹpẹ. On si wá, o si foribalẹ̀ fun Solomoni ọba: Solomoni si wi fun u pe, Mã lọ ile rẹ.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 1