Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 9:11-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Bi o ṣe ti Efraimu, ogo wọn yio fò lọ bi ẹiyẹ, lati ibí, ati lati inu, ati lati iloyun.

12. Bi nwọn tilẹ tọ́ ọmọ wọn dàgba, ṣugbọn emi o gbà wọn li ọwọ wọn, ti kì yio fi kù enia kan; lõtọ, egbe ni fun wọn pẹlu nigbati mo ba kuro lọdọ wọn!

13. Efraimu, bi mo ti ri Tirusi, li a gbìn si ibi daradara: ṣugbọn Efraimu yio bi ọmọ rẹ̀ fun apania.

14. Fun wọn, Oluwa, li ohun ti iwọ o fun wọn. Fun wọn ni iṣẹnu ati ọmú gbigbẹ́.

15. Gbogbo ìwa-buburu wọn mbẹ ni Gilgali; nitori nibẹ̀ ni mo korira wọn; nitori ìwa-buburu iṣe wọn, emi o le wọn kuro ni ile mi, emi kì yio fẹràn wọn mọ́; gbogbo ọmọ-alade wọn ni ọlọ̀tẹ.

16. A lù Efraimu, gbòngbo wọn gbẹ, nwọn kì yio so eso, bi nwọn tilẹ bi ọmọ, ṣugbọn emi o pa ãyò eso inu wọn.

17. Ọlọrun mi yio sọ wọn nù, nitoriti nwọn kò fetisi tirẹ̀; nwọn o si di alarinkiri lãrin awọn keferi.

Ka pipe ipin Hos 9