Gbogbo ìwa-buburu wọn mbẹ ni Gilgali; nitori nibẹ̀ ni mo korira wọn; nitori ìwa-buburu iṣe wọn, emi o le wọn kuro ni ile mi, emi kì yio fẹràn wọn mọ́; gbogbo ọmọ-alade wọn ni ọlọ̀tẹ.