Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 9:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MÁṢE yọ̀, Israeli, fun ayọ̀, bi awọn enia miràn: nitori iwọ ti ṣe agbère lọ kuro lọdọ Ọlọrun rẹ, iwọ ti fẹ́ èrè lori ilẹ ipakà gbogbo.

2. Ilẹ ipakà ati ohun ifunti kì yio bọ́ wọn, ọti-waini titun yio si tan ninu rẹ̀.

3. Nwọn kì yio gbe inu ilẹ Oluwa; ṣugbọn Efraimu yio padà si Egipti, nwọn o si jẹ ohun aimọ́ ni Assiria.

4. Nwọn kì yio ta Oluwa li ọrẹ ọti-waini, bẹ̃ni nwọn kì yio mu u ni inu dùn: ẹbọ wọn yio ri fun wọn bi onjẹ awọn ti nṣọ̀fọ; gbogbo awọn ti o jẹ ninu rẹ̀ ni yio di alaimọ́: nitori onjẹ wọn kì yio wá si ile Oluwa fun ọkàn wọn.

5. Kili ẹnyin o ṣe li ọjọ ti o ni irònu, ati li ọjọ àse Oluwa?

6. Nitori, sa wò o, nwọn ti lọ nitori ikogun: Egipti yio kó wọn jọ, Memfisi yio sin wọn: ibi didara fun fadakà wọn li ẹgún-ọ̀gan yio jogun wọn: ẹgún yio wà ninu agọ wọn.

7. Ọjọ ibẹ̀wo de, ọjọ ẹsan de; Israeli yio mọ̀: aṣiwère ni woli na, ẹni ẹmi na nsinwin; nitori ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ rẹ, ati irira nla na.

8. Olùṣọ Efraimu wà pẹlu Ọlọrun mi: ṣugbọn okùn pẹyẹpẹyẹ ni woli na li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, ati irira si ile Ọlọrun rẹ̀.

9. Nwọn ti ba ara wọn jẹ pupọ̀pupọ̀, bi li ọjọ Gibea: nitorina, on o ranti aiṣedẽde wọn, yio bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò.

10. Mo ri Israeli bi eso ajara li aginjù; mo ri awọn baba nyin bi akọpọ́n ninu igi ọpọ̀tọ li akọso rẹ̀: ṣugbọn nwọn tọ̀ Baal-peori lọ, nwọn si yà ara wọn si itiju nì; ohun irira wọn si ri gẹgẹ bi nwọn ti fẹ.

Ka pipe ipin Hos 9