Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 8:5-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ọmọ-malu rẹ ti ta ọ nù, Samaria; ibinu mi rú si wọn: yio ti pẹ to ki nwọn to de ipò ailẹ̀ṣẹ?

6. Nitori lati ọdọ Israeli wá li o ti ri bẹ̃ pẹlu; oniṣọ̀na li o ṣe e; nitorina on kì iṣe Ọlọrun: ṣugbọn ọmọ malu Samaria yio fọ tũtũ.

7. Nitori nwọn ti gbìn ẹfũfũ, nwọn o si ka ãjà: kò ni igi ọka: irúdi kì yio si mu onjẹ wá: bi o ba ṣepe o mu wá, alejò yio gbe e mì.

8. A gbe Israeli mì: nisisiyi ni nwọn o wà lãrin awọn Keferi bi ohun-elò ninu eyiti inu-didùn kò si.

9. Nitori nwọn goke lọ si Assiria, kẹtẹ́kẹtẹ́ igbẹ́ nikan fun ara rẹ̀: Efraimu ti bẹ̀ awọn ọrẹ li ọ̀wẹ.

10. Nitõtọ, bi nwọn tilẹ ti bẹ̀ ọ̀wẹ lãrin awọn orilẹ-ède, nisisiyi li emi o ko wọn jọ, nwọn o si kãnu diẹ fun ẹrù ọba awọn ọmọ-alade.

11. Nitori Efraimu ti tẹ́ pẹpẹ pupọ̀ lati dẹ̀ṣẹ, pẹpẹ yio jẹ ohun atidẹ̀ṣẹ fun u.

12. Mo ti kọwe ohun pupọ̀ ti ofin mi si i, ṣugbọn a kà wọn si bi ohun ajèji.

13. Nwọn rubọ ẹran ninu ẹbọ ẹran mi, nwọn si jẹ ẹ; Oluwa kò tẹwọgbà wọn; nisisiyi ni yio ránti ìwa-buburu wọn, yio si bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò: nwọn o padà lọ si Egipti.

14. Nitori Israeli ti gbagbe Ẹlẹda rẹ̀, o si kọ́ tempili pupọ; Juda si ti sọ ilu olodi di pupọ̀: ṣugbọn emi o rán iná kan si ori awọn ilu rẹ̀, yio si jẹ awọn ãfin rẹ̀ wọnni run.

Ka pipe ipin Hos 8