Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 5:8-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ẹ fun korneti ni Gibea, ati ipè ni Rama; kigbe kikan ni Bet-afeni, lẹhìn rẹ, iwọ Benjamini.

9. Efraimu yio di ahoro li ọjọ ibawi: ninu awọn ẹyà Israeli li emi ti fi ohun ti o wà nitõtọ hàn.

10. Awọn olori Juda dàbi awọn ti o yẹ̀ oju àla: lara wọn li emi o tú ibinu mi si bi omi.

11. A tẹ̀ ori Efraimu ba, a si ṣẹgun rẹ̀ ninu idajọ, nitoriti on mọ̃mọ̀ tẹ̀le ofin na.

12. Nitorina ni emi o ṣe dabi kòkoro aṣọ si Efraimu, ati si ile Juda bi idin.

13. Nigbati Efraimu ri arùn rẹ̀, ti Juda si ri ọgbẹ́ rẹ̀, nigbana ni Efraimu tọ̀ ara Assiria lọ, o si ranṣẹ si ọba Jarebu; ṣugbọn on kò le mu ọ lara da, bẹ̃ni kò le wò ọgbẹ́ rẹ jiná.

14. Nitori emi o dàbi kiniun si Efraimu, ati bi ọmọ kiniun si ile Juda, emi, ani emi o fàya, emi o si lọ, emi o mu lọ, ẹnikẹni kì yio si gbà a silẹ.

15. Emi o padà lọ si ipò mi, titi nwọn o fi jẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn, ti nwọn o si wá oju mi: ninu ipọnju wọn, nwọn o wá mi ni kùtukùtu.

Ka pipe ipin Hos 5