Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 5:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ gbọ́ eyi, ẹnyin alufa: si tẹtilelẹ ẹnyin ile Israeli; ki ẹ si gbọ́, ile ọba na; nitori idajọ kàn nyin, nitoriti ẹnyin ti jẹ ẹgẹ́ si Mispa, àwọn ti a nà silẹ lori Tabori.

2. Awọn ọlọ̀tẹ si jinlẹ ni pipanirun, emi o jẹ olùbawi gbogbo wọn.

3. Emi mọ̀ Efraimu, Israeli kò si pamọ́ fun mi: nitori nisisiyi, Efraimu, iwọ ṣe agbère, Israeli si dibajẹ.

4. Iṣe wọn kì o jọ̀wọ wọn lati yipadà si Ọlọrun wọn: nitori ẹmi agbère wà lãrin wọn, nwọn kò si mọ̀ Oluwa.

5. A si rẹ̀ ogo Israeli silẹ loju ara rẹ̀; nitorina ni Israeli ati Efraimu yio ṣubu ninu aiṣedẽde wọn, Juda yio si ṣubu pẹlu wọn.

6. Nwọn o lọ ti awọn ti agbo-ẹran wọn ati ọ̀wọ ẹran wọn lati wá Oluwa: ṣugbọn nwọn kì o ri i, on ti fà ara rẹ̀ sẹhìn kuro lọdọ wọn.

Ka pipe ipin Hos 5