Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 4:14-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Emi kì yio ba awọn ọmọbinrin nyin wi nigbati nwọn ba ṣe agbère, tabi awọn afẹ́sọnà nyin nigbati nwọn ba ṣe panṣagà: nitori nwọn yà si apakan pẹlu awọn agbère, nwọn si mba awọn panṣagà rubọ̀: nitorina awọn enia ti kò ba moye yio ṣubu.

15. Bi iwọ, Israeli, ba ṣe agbère, máṣe jẹ ki Juda ṣẹ̀; ẹ má si wá si Gilgali, bẹ̃ni ki ẹ má si goke lọ si Bet-afeni, bẹ̃ni ki ẹ má si bura pe, Oluwa mbẹ.

16. Nitori Israeli ṣe agidi bi ọmọ malu alagidi; nisisiyi Oluwa yio bọ́ wọn bi ọdọ-agùtan ni ibi ayè nla.

17. Efraimu dapọ̀ mọ òriṣa: jọwọ rẹ̀ si.

18. Ohun mimu wọn di kikan: nwọn ṣe agbère gidigidi; awọn olori rẹ̀ fẹ itìju, ẹ bun u li ayè.

19. Afẹfẹ ti dè e pẹlu mọ iyẹ́ apa rẹ̀, nwọn o si tíju nitori ẹbọ wọn.

Ka pipe ipin Hos 4