Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 2:2-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ẹ ba iya nyin wijọ, ẹ wijọ; nitori on kì iṣe aya mi, bẹ̃ni emi kì iṣe ọkọ rẹ̀: nitori na jẹ ki on ki o mu gbogbo agberè rẹ̀ kuro ni iwaju rẹ̀, ati gbogbo panṣaga rẹ̀ kuro larin ọyàn rẹ̀.

3. Ki emi má ba tú u si ihòho, emi o si gbe e kalẹ bi ọjọ ti a bi i, emi o si ṣe e bi ijù, emi o si gbe e kalẹ bi ilẹ gbigbẹ, emi o si fi ongbẹ pa a kú.

4. Emi kì yio si ṣãnu fun awọn ọmọ rẹ̀; nitoriti nwọn jẹ́ ọmọ agbère.

5. Nitoriti iya wọn ti hùwa agbère: ẹniti o loyun wọn ti ṣe ohun itiju: nitori ti o wipe, Emi o tun tọ̀ awọn ayànfẹ́ mi lẹhìn, ti nfun mi ni onjẹ mi ati omi mi, irun agùtan mi ati ọgbọ̀ mi, ororo mi, ati ohun mimu mi.

6. Nitorina kiyesi i, emi o fi ẹgún sagbàra yi ọ̀na rẹ̀ ka, emi o si mọ odi, ti on kì yio fi ri ọ̀na rẹ̀ mọ.

7. On o si lepa awọn ayànfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kì yio le ba wọn; on o si wá wọn, ṣugbọn kì yio ri wọn: nigbana ni yio wipe, Emi o padà tọ̀ ọkọ mi iṣãju lọ; nitoriti o sàn fun mi nigbana jù ti isisiyi lọ.

8. Nitori on kò ti mọ̀ pe emi li ẹniti o fun u li ọkà, ati ọti-waini titun, ati ororo; ti mo si mu fàdakà ati wurà rẹ̀ pọ̀ si i, ti nwọn fi ṣe Baali.

Ka pipe ipin Hos 2