Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 2:13-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Emi o si bẹ̀ ọjọ Baalimu wò li ara rẹ̀, ninu eyiti on fi turari joná fun wọn, ti on si fi oruka eti, ati ohun ọ̀ṣọ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọṣọ, ti on si tọ̀ awọn ayànfẹ́ lẹhìn lọ, ti on si gbagbe mi, ni Oluwa wi.

14. Nitorina, kiyesi i, emi o tàn a, emi o si mu u wá si aginjù, emi o si sọ̀rọ itùnu fun u.

15. Emi o si fun u ni ọgbà àjara rẹ̀ lati ibẹ̀ wá, ati afonifojì Akori fun ilẹ̀kun ireti: on o si kọrin nibẹ̀, bi li ọjọ ewe rẹ̀, ati bi li ọjọ ti o jade lati ilẹ Egipti wá.

16. Yio si ṣe li ọjọ na, iwọ o pè mi ni Iṣi; iwọ kì yio si pè mi ni Baali mọ, ni Oluwa wi,

17. Nitori emi o mu orukọ awọn Baali kuro li ẹnu rẹ̀, a kì yio si fi orukọ wọn ranti wọn mọ́.

18. Li ọjọ na li emi o si fi awọn ẹranko igbẹ, ati ẹiyẹ oju ọrun, ati ohun ti nrakò lori ilẹ da majẹmu fun wọn, emi o si ṣẹ́ ọrun ati idà ati ogun kuro ninu aiye, emi o si mu wọn dubulẹ li ailewu.

19. Emi o si fẹ́ ọ fun ara mi titi lai; nitõtọ, emi o si fẹ́ ọ fun ara mi ni ododo, ni idajọ, ati ni iyọ́nu, ati ni ãnu.

20. Emi o tilẹ fẹ́ ọ fun ara mi ni otitọ, iwọ o si mọ̀ Oluwa.

Ka pipe ipin Hos 2