Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 10:7-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Bi o ṣe ti Samaria, a ké ọba rẹ̀ kuro bi ifõfõ loju omi.

8. Ibi giga Afeni pẹlu, ẹ̀ṣẹ Israeli, li a o parun; ẹgún ọ̀gan on oṣuṣu yio hù jade lori pẹpẹ wọn; nwọn o si wi fun awọn oke-nla pe, Bò wa mọlẹ; ati fun awọn oke kékèké pe, Wó lù wa.

9. Lati ọjọ Gibea ni iwọ ti ṣẹ̀, Israeli: nibẹ̀ ni nwọn duro: ogun Gibea si awọn ọmọ ẹ̀ṣẹ kò ha le wọn ba?

10. Ifẹ inu mi ni ki nle nà wọn; a o si gbá awọn enia jọ si wọn, lati di ara wọn si ẹ̀ṣẹ wọn mejeji.

11. Efraimu si dabi ọmọ-malu ti a kọ́, ti o si fẹ́ lati ma tẹ ọkà; ṣugbọn emi rekọja li ori ọrùn rẹ̀ ti o ni ẹwà: emi o mu ki Efraimu gùn ẹṣin; Juda yio tú ilẹ, Jakobu yio si fọ́ ogulùtu rẹ̀.

12. Ẹ furùngbin fun ara nyin li ododo, ẹ ká li ãnu: ẹ tú ilẹ nyin ti a kò ro: nitori o to akokò lati wá Oluwa, titi yio fi de, ti yio si fi rọ̀jo ododo si nyin.

Ka pipe ipin Hos 10