Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Est 9:18-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ṣugbọn awọn Ju ti mbẹ ni Ṣuṣani kó ara wọn jọ li ọjọ kẹtala rẹ̀, ati li ọjọ kẹrinla rẹ̀; ati li ọjọ kẹ̃dogun rẹ̀ nwọn simi, nwọn si ṣe e li ọjọ àse ati inu didùn.

19. Nitorina awọn Ju ti o wà ni iletò wọnni, ti nwọn ngbe ilu ti kò li odi, nwọn ṣe ọjọ kẹrinla oṣù Adari li ọjọ inu-didùn, ati àse, ati ọjọ rere, ati ọjọ ti olukulùku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀.

20. Mordekai si kọwe nkan wọnyi, o si fi iwe ranṣẹ si gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, si awọn ti o sunmọ etile, ati awọn ti o jina.

21. Lati fi eyi lelẹ larin wọn, ki nwọn ki o le ma pa ọjọ kẹrinla oṣù Adari, ati ọjọ kẹ̃dogun rẹ̀ mọ́ li ọdọdun.

22. Bi ọjọ lọwọ eyiti awọn Ju simi kuro ninu awọn ọta wọn, ati oṣù ti a sọ ibanujẹ wọn di ayọ̀, ati ọjọ ọ̀fọ di ọjọ rere; ki nwọn ki o le sọ wọn di ọjọ àse, ati ayọ̀, ati ọjọ ti olukuluku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀, ati ẹbun fun awọn talaka.

23. Awọn Ju si gbà lati ṣe bi nwọn ti bẹ̀rẹ si iṣe, ati bi Mordekai si ti kọwe si wọn.

24. Pe, Hamani ọmọ Medata, ara Agagi nì, ọta gbogbo awọn Ju ti gbiro lati pa awọn Ju run, o si ti da Puri, eyinì ni ibo, lati pa wọn, ati lati run wọn;

25. Ṣugbọn nigbati Esteri tọ̀ ọba wá, o fi iwe paṣẹ pe, ki ete buburu ti a ti pa si awọn Ju ki o le pada si ori on tikalarẹ̀, ati ki a so ati on ati awọn ọmọ rẹ̀ rọ̀ sori igi.

26. Nitorina ni nwọn ṣe npè ọjọ wọnni ni Purimu bi orukọ Puri. Nitorina gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ inu iwe yi, ati nitori gbogbo eyi ti oju wọn ti ri nitori ọ̀ran yi, ati eyiti o ti ba wọn,

27. Awọn Ju lanà rẹ̀, nwọn si gbà a kanri wọn, ati fun iru-ọmọ wọn, ati fun gbogbo awọn ti o dà ara wọn pọ̀ mọ wọn, pe ki o máṣe yẹ̀, ki nwọn ki o ma pa ọjọ mejeji wọnyi mọ́ gẹgẹ bi ikọwe wọn, ati gẹgẹ bi akokò wọn ti a yàn lọdọdun.

28. Ati pe, ki nwọn ma ranti ọjọ wọnyi, ki nwọn si ma kiyesi i ni irandiran wọn gbogbo; olukuluku idile, olukuluku ìgberiko, ati olukuluku ilu; ati pe, ki Purimu wọnyi ki o máṣe yẹ̀ larin awọn Ju, tabi ki iranti wọn ki o máṣe parun ninu iru-ọmọ wọn.

29. Nigbana ni Esteri ayaba, ọmọbinrin Abihaili, ati Mordekai, ara Juda, fi ọlá gbogbo kọwe, lati fi idi iwe keji ti Purimu yi mulẹ.

30. O si fi iwe ranṣẹ si gbogbo awọn Ju, si ẹtadilãdoje ìgberiko ijọba Ahaswerusi, ọ̀rọ alafia ati otitọ.

31. Lati fi idi ọjọ Purimu wọnyi mulẹ, li akokò wọn ti a yàn gẹgẹ bi Mordekai, ara Juda, ati Esteri ayaba ti paṣẹ fun wọn, ati bi nwọn ti pinnu rẹ̀ fun ara wọn, ati fun iru-ọmọ wọn, ọ̀ran ãwẹ ati ẹkún wọn.

Ka pipe ipin Est 9