Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Est 2:17-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ọba si fẹràn Esteri jù gbogbo awọn obinrin lọ, on si ri ore-ọfẹ ati ojurere lọdọ rẹ̀ jù gbogbo awọn wundia na lọ; tobẹ̃ ti o fi gbe ade ọba kà a li ori, o si fi i ṣe ayaba ni ipò Faṣti.

18. Ọba si sè àse nla kan fun gbogbo awọn olori rẹ̀, ati awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ani àse ti Esteri; o si fi isimi fun awọn ìgberiko rẹ̀, o si ṣe itọrẹ gẹgẹ bi ọwọ ọba ti to.

19. Nigbati a si kó awọn wundia na jọ li ẹrinkeji, nigbana ni Mordekai joko li ẹnu ọ̀na ile ọba.

20. Esteri kò ti ifi awọn ibatan, tabi awọn enia rẹ̀ hàn titi disisiyi bi Mordekai ti paṣẹ fun u: nitori Esteri npa ofin Mordekai mọ́, bi igba ti o wà li abẹ itọ́ rẹ̀.

21. Li ọjọ wọnni, nigbati Mordekai njoko li ẹnu ọ̀na ile ọba, meji ninu awọn iwẹfa ọba, Bigtani ati Tereṣi, ninu awọn ti nṣọ iloro, nwọn binu, nwọn si nwá ọ̀na lati gbe ọwọ le Ahaswerusi ọba.

22. Nkan na si di mimọ̀ fun Mordekai, o si sọ fun Esteri ayaba; Esteri si fi ọ̀ran na hàn ọba li orukọ Mordekai.

23. Nigbati nwọn si wadi ọ̀ran na, nwọn ri idi rẹ̀; nitorina a so awọn mejeji rọ̀ sori igi; a si kọ ọ sinu iwé-iranti niwaju ọba.

Ka pipe ipin Est 2