Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esr 5:6-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Atunkọ iwe da ti Tatnai, bãlẹ ni ihahin-odò, ati Ṣetar-bosnai, ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ rán si Dariusi ọba: awọn ara Afarsaki ti ihahin-odò.

7. Nwọn fi iwe ranṣẹ si i, ninu eyiti a kọ bayi; Si Dariusi, ọba, alafia gbogbo.

8. Ki ọba ki o mọ̀ pe, awa lọ si igberiko Judea si ile Ọlọrun ẹniti o tobi, ti a fi okuta nlanla kọ, a si tẹ igi si inu ogiri na, iṣẹ yi nlọ siwaju kánkán, o si nṣe rere li ọwọ wọn.

9. Nigbana ni awa bi awọn àgba wọnni li ère, a si wi fun wọn bayi pe, Tani fun nyin li aṣẹ lati kọ́ ile yi, ati lati mọ odi yi?

10. Awa si bère orukọ wọn pẹlu, lati mu ki o da ọ li oju, ki a le kọwe orukọ awọn enia ti iṣe olori ninu wọn.

11. Bayi ni nwọn si fi èsi fun wa wipe, Iranṣẹ Ọlọrun ọrun on aiye li awa iṣe, awa si nkọ́ ile ti a ti kọ́ li ọdun pupọ wọnyi sẹhin, ti ọba nla kan ni Israeli ti kọ́, ti o si ti pari.

12. Ṣugbọn nitoriti awọn baba wa mu Ọlọrun ọrun binu, o fi wọn le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babiloni ti Kaldea, ẹniti o wó ile yi palẹ, ti o si kó awọn enia na lọ si Babiloni.

Ka pipe ipin Esr 5