Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 8:7-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na agbala; nigbati mo si wò, kiye si i iho lara ogiri.

8. Nigbana li o wi fun mi pe, Ọmọ enia, dá ogirí na lu nisisiyi: nigbati mo si ti dá ogiri na lu tan, kiye si i, ilẹkun.

9. O si wi fun mi pe, Wọ ile, ki o si wo ohun irira buburu ti nwọn nṣe nihin.

10. Bẹ̃ni mo wọle, mo si ri; si kiye si i, gbogbo aworan ohun ti nrakò, ati ẹranko irira, ati gbogbo oriṣa ile Israeli li a yá li aworan lara ogiri yika kiri.

11. Adọrin ọkunrin ninu awọn agbà ile Israeli si duro niwaju wọn, Jaasania ọmọ Ṣafani si duro lãrin wọn, olukuluku pẹlu awo turari lọwọ rẹ̀; ẹ̃fin ṣiṣu dùdu ti turari si goke lọ.

12. Nigbana li o si wi fun mi pe, Ọmọ enia iwọ ri ohun ti awọn agbà ile Israeli nṣe li okunkùn, olukuluku ninu iyará oriṣa tirẹ̀? nitori nwọn wipe, Oluwa kò ri wa; Oluwa ti kọ̀ aiye silẹ.

13. O si wi fun mi pe, Tun yipada, iwọ o si ri ohun irira ti o tobi jù yi ti nwọn nṣe.

14. Nigbana li o mu mi wá si ilẹkun ẹnu-ọ̀na ile Oluwa, ti o wà nihà ariwa; si kiye si i, awọn obinrin joko nwọn nsọkun fun Tammusi.

15. Nigbana li o sọ fun mi pe, Iwọ ri eyi, Iwọ ọmọ enia? tun yipada, iwọ o si ri ohun irira ti o tobi ju wọnyi lọ.

Ka pipe ipin Esek 8