Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 6:3-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Si wipe, Ẹnyin oke-nla Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun; bayi li Oluwa Ọlọrun wi si awọn oke-nla, si awọn oke kekeke, si awọn odò siṣàn, ati si awọn afonifoji; kiyesi i, Emi, ani Emi, o mu idà wá sori nyin, emi o si pa ibi giga nyin run.

4. Pẹpẹ nyin yio si di ahoro, ere nyin yio si fọ; okú nyin li emi o si gbe jù siwaju oriṣa nyin.

5. Emi o si tẹ́ okú awọn ọmọ Israeli siwaju oriṣa wọn; emi o si tú egungun nyin ka yi pẹpẹ nyin ka.

6. Ilu-nla li a o parun ninu gbogbo ibugbe nyin, ibi giga yio si di ahoro: ki a le run pẹpẹ nyin, ki a si sọ ọ di ahoro, ki a si le fọ́ oriṣa nyin, ki o si tan, ki a si le ké ere nyin lu ilẹ, ki iṣẹ́ nyin si le parẹ.

7. Okú yio si ṣubu li ãrin nyin, ẹnyin o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.

8. Ṣugbọn emi o fi iyokú silẹ, ki ẹnyin le ni diẹ ti yio bọ́ lọwọ idà lãrin awọn orilẹ-ède, nigbati a o tú nyin ka gbogbo ilẹ.

9. Awọn ti o bọ́ ninu nyin yio si ranti mi, lãrin awọn orilẹ-ède nibiti nwọn o gbe dì wọn ni igbekun lọ, nitoriti mo ti fọ́ ọkàn agbere wọn ti o ti lọ kuro lọdọ mi, ati pẹlu oju wọn, ti nṣagbere lọ sọdọ oriṣa wọn: nwọn o si sú ara wọn nitori ìwa ibi ti nwọn ti hù ninu gbogbo irira wọn.

10. Nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, emi kò wi lasan pe, emi o ṣe ibi yi si wọn.

11. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; pàtẹwọ rẹ, si fi ẹsẹ rẹ kì ilẹ; si wipe, o ṣe! fun gbogbo irira buburu ilẹ Israeli, nitori nwọn o ṣubu nipa idà, nipa ìyan, ati nipa ajakalẹ àrun.

Ka pipe ipin Esek 6