Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 48:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. WỌNYI si ni orukọ awọn ẹ̀ya na. Lati opin ariwa titi de ọwọ́ ọ̀na Hetlonu, bi a ba nlọ si Hamati, Hasaenani, leti Damasku niha ariwa, de ọwọ́ Hamati; wọnyi sa ni ihà rẹ̀ ni ila-õrun ati iwọ-õrun; ipin kan fun Dani.

2. Ati ni àgbegbe Dani, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Aṣeri.

3. Ati ni àgbegbe Aṣeri, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Naftali.

4. Ati ni àgbegbe Naftali, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Manasse.

5. Ati ni àgbegbe Manasse, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Efraimu.

6. Ati ni àgbegbe Efraimu, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Reubeni.

7. Ati ni àgbegbe Reubeni, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Juda.

Ka pipe ipin Esek 48