Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 47:16-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Hamati, Berota, Sibraimu, ti o wà lãrin ãlà Damasku, ati ãlà Hamati; Hasar-hatikonu, ti o wà ni agbègbe Haurani.

17. Alà lati okun yio si jẹ Hasarenani, ãlà Damasku, ati ariwa nihà ariwa, ati ãlà Hamati. Eyi si ni ihà ariwa.

18. Ati ni ihà ila-õrun ẹ o wọ̀n lati ãrin Haurani, ati lati ãrin Damasku, ati lati ãrin Gileadi, ati lati ãrin ilẹ Israeli lẹba Jordani, lati ãlà titi de okun ila-õrun. Eyi ni ihà ila-õrun.

19. Ati ihà gusu si gusu, lati Tamari titi de omi ijà ni Kadeṣi, pẹ̀tẹlẹ si okun nla. Eyi ni ihà gusu.

20. Ihà iwọ-õrun pẹlu yio jẹ okun nla lati ãlà bi a ti nlọ si Hamati. Eyi ni ihà iwọ-õrun.

21. Bayi li ẹ o pin ilẹ yi fun ara nyin gẹgẹ bi awọn ẹ̀ya Israeli.

22. Yio si ṣe pe, ìbo ni ẹ o fi pin i ni ogún fun ara nyin, ati fun awọn alejo ti o ṣe atipo lãrin nyin, ti nwọn bi ọmọ lãrin nyin: nwọn o si ri si nyin bi ibilẹ ninu awọn ọmọ Israeli; nwọn o ba nyin pin i li ogún lãrin awọn ẹ̀ya Israeli.

23. Yio si ṣe pe, ni ẹ̀ya ti alejò ba ṣe atipo, nibẹ̀ li ẹ o fun u ni ogún, ni Oluwa Ọlọrun wi.

Ka pipe ipin Esek 47