Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 47:12-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ati lẹba odò ni eti rẹ̀, ni ihà ihin ati ni ihà ọhun, ni gbogbo igi jijẹ yio hù, ti ewe rẹ̀ kì yio rọ, ti eso rẹ̀ kì yio si run: yio ma so eso titun rẹ̀ li oṣù rẹ̀, nitori omi wọn lati ibi mimọ́ ni nwọn ti ntú jade: eso rẹ̀ yio si jẹ fun jijẹ, ati ewe rẹ̀ fun imunilaradá.

13. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; eyi ni yio jẹ ãlà, ti ẹnyin o fi jogún ilẹ na fun ara nyin fun ẹ̀ya mejila Israeli: Josefu yio ni ipin meji.

14. Ẹnyin o si jogún rẹ̀, olukuluku bi ti ekeji rẹ̀: eyiti mo ti gbe ọwọ́ mi sokè lati fi i fun awọn baba nyin: ilẹ yi yio si bọ sọdọ nyin fun ogún.

15. Eyi ni yio si jẹ ãlà ilẹ na nihà ariwa, lati okun nla, ni ọ̀na Hetloni, bi a ti nlọ si Sedadi;

16. Hamati, Berota, Sibraimu, ti o wà lãrin ãlà Damasku, ati ãlà Hamati; Hasar-hatikonu, ti o wà ni agbègbe Haurani.

17. Alà lati okun yio si jẹ Hasarenani, ãlà Damasku, ati ariwa nihà ariwa, ati ãlà Hamati. Eyi si ni ihà ariwa.

18. Ati ni ihà ila-õrun ẹ o wọ̀n lati ãrin Haurani, ati lati ãrin Damasku, ati lati ãrin Gileadi, ati lati ãrin ilẹ Israeli lẹba Jordani, lati ãlà titi de okun ila-õrun. Eyi ni ihà ila-õrun.

19. Ati ihà gusu si gusu, lati Tamari titi de omi ijà ni Kadeṣi, pẹ̀tẹlẹ si okun nla. Eyi ni ihà gusu.

Ka pipe ipin Esek 47