Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 46:16-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Bi olori na ba fi ẹbùn fun ẹnikẹni ninu awọn ọmọ rẹ̀, ogún rẹ̀ yio jẹ ti awọn ọmọ rẹ̀; yio jẹ ini wọn nipa ijogun.

17. Bi o ba si fi ẹbùn ninu ini rẹ̀ fun ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, nigbana yio jẹ tirẹ̀ titi di ọdun omnira; yio si tun pada di ti olori na: ṣugbọn ogún rẹ̀ yio jẹ ti awọn ọmọ rẹ̀ fun wọn.

18. Olori na kì yio si fi ipá mu ninu ogún awọn enia lati le wọn jade kuro ninu ini wọn, yio fi ogún fun awọn ọmọ rẹ̀ lara ini ti ontikalarẹ̀: ki awọn enia mi ki o má ba tuká, olukuluku kuro ni ini rẹ̀.

19. O si mu mi kọja li abawọ̀, ti o wà lẹba ẹnu-ọ̀na, si awọn yará mimọ́ ti awọn alufa, ti o kọjusi ariwa: si kiyesi i, ibi kan wà nibẹ̀ ni ihà mejeji iwọ-õrun.

20. O si wi fun mi pe, Eyi ni ibiti awọn alufa yio ma sè ọrẹ irekọja ati ọrẹ ẹ̀ṣẹ, nibiti nwọn o ma yan ọrẹ jijẹ; ki nwọn má ba gbe wọn jade si agbalá ode, lati sọ awọn enia di mimọ́.

21. O si mu mi jade wá si agbalá ode, o si mu mi kọja ni igun mẹrẹrin agbalá na; si kiyesi i, ni olukuluku igun agbalá na ni agbala kan gbe wà.

22. Ni igun mẹrẹrin agbalá na, ni agbalá ti a kànpọ ologoji igbọnwọ ni gigùn, ati ọgbọ̀n ni ibú: awọn igun mẹrẹrin wọnyi jẹ iwọ̀n kanna.

23. Ọwọ́ ile kan si wà yika ninu wọn, yika awọn mẹrẹrin, a si ṣe ibudaná si abẹ ọwọ́ na yika.

24. O si wi fun mi pe, Wọnyi ni ibi awọn ti nsè, nibiti awọn iranṣẹ ile na yio ma se ẹbọ awọn enia.

Ka pipe ipin Esek 46