Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 42:6-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nitori nwọn jẹ olorule mẹta, ṣugbọn nwọn kò ni ọwọ̀n bi ọwọ̀n agbalá: nitorina a fasẹhin kuro ninu yará isalẹ ati kuro ninu yará ãrin lati ilẹ wá.

7. Ati ogiri ti o wà lode ti o kọju si yará, li apa agbala ode niwaju yará, gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ.

8. Nitori gigùn awọn yará ti o wà lode jẹ ãdọta igbọnwọ: si wò o, niwaju tempili o jẹ ọgọrun igbọnwọ.

9. Ati lati isalẹ yará wọnyi ni iwọle li ọ̀na ila-õrun wà, bi a ti nlọ sinu wọn lati agbala ode wá.

10. Ni ibú ogiri agbala, li ọ̀na ila-õrun niwaju ibiti a yà sọtọ̀, ati niwaju ile na, ni awọn yará na wà.

11. Ati ọ̀na iwaju wọn ti gẹgẹ bi iri awọn yará ti o wà li ọ̀na ariwa, bi nwọn ti gùn mọ, bẹ̃ ni nwọn gbòro mọ: ati gbogbo ijade wọn si dabi iṣe wọn, ati bi ilẹkùn wọn.

12. Bẹ̃ gẹgẹ ni yará ti on ti ilẹkùn wọn li ọ̀na gusu, ilẹkùn kan wà lori ọ̀na, li ọ̀na gbọran niwaju ogiri li ọ̀na ila-õrun bi a ti nwọ̀ inu wọn.

13. O si wi fun mi pe, Awọn yará ariwa ati awọn yará gusu, ti o wà niwaju ibiti a yà sọtọ̀, awọn ni yará mimọ́, nibiti awọn alufa ti nsunmọ Oluwa yio ma jẹ ohun mimọ́ julọ: nibẹ̀ ni nwọn o ma gbe ohun mimọ́ julọ kà, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja; nitori ibẹ̀ jẹ mimọ́.

14. Nigbati awọn alufa ba wọ̀ ibẹ̀, nwọn kì yio si kuro ni ibi mimọ́ si agbala ode, ṣugbọn nibẹ nibiti nwọn gbe nṣiṣẹ ni nwọn o fi ẹwù wọn si; nitori nwọn jẹ mimọ́; nwọn o si wọ̀ ẹwù miran, nwọn o si sunmọ nkan wọnni ti o jẹ́ ti enia.

15. Nigbati o si ti wọ̀n ile ti inu tan, o mu mi wá sihà ilẹkùn ti o kọju si ọ̀na ila-õrun, o si wọ̀n yika.

16. O fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa ila-õrun, ẹ̃dẹgbẹta ije, nipa ije iwọ̀nlẹ yika.

17. O si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa ariwa, ẹ̃dẹgbẹta ije yika.

Ka pipe ipin Esek 42