Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 41:14-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Ati ibú oju ile na, ati ti ibi ti a yà sọtọ̀ nihà ila-õrun ọgọrun igbọnwọ.

15. O si wọ̀n gigun ile na ti o kọju si ibiti a yà sọtọ̀ ti mbẹ lẹhin rẹ̀, ati ibujoko-oke ni ihà kan ati nihà miran, ọgọrún igbọnwọ, pẹlu tempeli inu, ati iloro agbalá na;

16. Awọn iloro, ati ferese toro, ati ibujoko oke yika lori ile olorule mẹta wọn, ti o wà niwaju iloro na, li a fi igi tẹ́ yika, ati lati ilẹ de oke ferese, a si bò awọn ferese na;

17. Si ti oke ilẹkun ani titi de ile ti inu, ati ti ode, ati lara ogiri niha gbogbo tinu tode ni wiwọ̀n.

18. Kerubu ati igi ọpẹ li a si fi ṣe e, igi ọpẹ kan si mbẹ lãrin kerubu ati kerubu: kerubu kọkan si ni oju meji;

19. Oju enia kan si wà nihà ibi igi ọpe li apa kan, ati oju ẹgbọ̀rọ kiniun kan si wà nihà ibi igi ọpẹ li apa keji: a ṣe e yi ile na ka niha gbogbo.

20. Lati ilẹ titi fi de okè ilẹkùn, ni a ṣe kerubu ati igi ọpẹ si, ati lara ogiri tempili na.

21. Awọn opó ilẹkùn tempili na jẹ igun mẹrin lọgbọgba: ati iwaju ibi mimọ́ irí ọkan bi irí ekeji.

22. Pẹpẹ igi na jẹ igbọnwọ mẹta ni giga, gigùn rẹ̀ igbọnwọ meji; ati igun rẹ̀, ati gigùn rẹ̀, ati awọn ogiri rẹ̀ jẹ ti igi: o si wi fun mi pe, Eyi ni tabili ti mbẹ niwaju Oluwa.

23. Ati tempili na, ati ibi mimọ́ na, ni ilẹkùn meji.

24. Awọn ilẹkùn mejeji na ni awẹ, awẹ meji ti nyi; awẹ meji fun ilẹkùn kan, ati awẹ meji fun ilẹkùn keji.

25. Kerubu, ati igi ọpẹ li a ṣe si ara wọn, sara ilẹkùn tempili, gẹgẹ bi eyiti a ṣe sara ogiri; igi ibori wà loju iloro lode.

26. Ferese toro ati igi ọpẹ mbẹ nihà ihin ati nihà ọhun nihà iloro, ati ni yará-iha ile na, ati ni igi ibori.

Ka pipe ipin Esek 41