Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 4:9-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Si mu alikama, ati ọka bàba, erẽ ati lentile ati milleti, ati ẹwẹ, fi wọn sinu ikoko kan, ki o si fi wọn ṣe akara, gẹgẹ bi iye ọjọ ti iwọ o dubulẹ li ẹgbẹ́ rẹ, ẹwa-di-ni-irinwo ọjọ ni iwọ o jẹ ninu rẹ̀.

10. Iwọ o si jẹ onjẹ rẹ nipa ìwọn, ogún ìwọn ṣekeli li ọjọ kan, lati akoko de akoko ni iwọ o jẹ ẹ.

11. Iwọ o si mu omi nipa ìwọn, idamẹfa oṣuwọ̀n hini kan: lati akoko de akoko ni iwọ o mu u.

12. Iwọ o si jẹ ẹ bi akara ọka bàba, iwọ o si fi igbẹ́ enia din i, li oju wọn.

13. Oluwa si wipe, Bayi li awọn ọmọ Israeli yio jẹ akara aimọ́ wọn larin awọn keferi, nibiti emi o le wọn lọ.

14. Nigbana ni mo wipe, A, Oluwa Ọlọrun! kiye si i, a kò ti sọ ọkàn mi di aimọ́: nitori lati igba ewe mi wá titi di isisiyi, emi kò ti ijẹ ninu ohun ti o kú fun ara rẹ̀, tabi ti a faya pẹrẹpẹrẹ, bẹ̃ni ẹran ẽwọ̀ kò iti iwọ̀ mi li ẹnu ri.

15. Nigbana ni o wi fun mi pe, Wõ, mo ti fi ẹlẹbọtọ fun ọ dipò igbẹ́ enia, iwọ o si fi ṣe akara rẹ.

16. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, kiye si i, emi o ṣẹ ọpá onjẹ ni Jerusalemu: nwọn o si jẹ akara nipa ìwọn, ati pẹlu itọju; nwọn o si mu omi nipa ìwọn ati pẹlu iyanu.

17. Ki nwọn ki o le ṣe alaini akara ati omi, ki olukuluku wọn ki o le yanu si ọmọ-nikeji rẹ̀, ki nwọn si run nitori ẹ̀ṣẹ wọn.

Ka pipe ipin Esek 4