Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 36:21-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Ṣugbọn ãnu orukọ mimọ́ mi ṣe mi, ti ile Israeli ti bajẹ lãrin awọn keferi, nibiti nwọn lọ.

22. Nitorina sọ fun ile Israeli, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ile Israeli, emi kò ṣe eyi nitori ti nyin, ṣugbọn fun orukọ mimọ́ mi, ti ẹnyin ti bajẹ lãrin awọn keferi, nibiti ẹnyin lọ.

23. Emi o si sọ orukọ nla mi di mimọ́, ti a bajẹ lãrin awọn keferi, ti ẹnyin ti bajẹ lãrin wọn; awọn keferi yio si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati a o sọ mi di mimọ́ ninu nyin niwaju wọn, li Oluwa Ọlọrun wi.

24. Nitori emi o mu nyin kuro lãrin awọn keferi, emi o si ṣà nyin jọ kuro ni gbogbo ilẹ, emi o si mu nyin padà si ilẹ ti nyin.

25. Nigbana ni emi o fi omi mimọ́ wọ́n nyin, ẹnyin o si mọ́: emi o si wẹ̀ nyin mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin nyin ati kuro ninu gbogbo oriṣa nyin.

26. Emi o fi ọkàn titun fun nyin pẹlu, ẹmi titun li emi o fi sinu nyin, emi o si mu ọkàn okuta kuro lara nyin, emi o si fi ọkàn ẹran fun nyin.

27. Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, emi o si mu ki ẹ ma rìn ninu aṣẹ mi, ẹnyin o pa idajọ mi mọ, ẹ o si ma ṣe wọn.

28. Ẹnyin o si ma gbe ilẹ ti emi fi fun awọn baba nyin; ẹnyin o si ma jẹ enia mi, emi o si ma jẹ Ọlọrun nyin.

29. Emi o si gbà nyin là kuro ninu aimọ́ nyin gbogbo: emi o si pè ọkà wá, emi o si mu u pọ̀ si i, emi kì yio si mu ìyan wá ba nyin.

30. Emi o si sọ eso-igi di pupọ̀, ati ibísi oko, ki ẹ má bà gbà ẹ̀gan ìyan mọ lãrin awọn keferi.

31. Nigbana li ẹnyin o ranti ọ̀na buburu nyin, ati iṣe nyin ti kò dara, ẹ o si sú ara nyin li oju ara nyin fun aiṣedẽde nyin, ati fun irira nyin.

32. Kì iṣe nitori ti nyin li emi ṣe eyi, ni Oluwa Ọlọrun wi, ẹ mọ̀ eyi: ki oju ki o tì nyin, ki ẹ si dãmú nitori ọ̀na ara nyin, ile Israeli.

33. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Li ọjọ ti emi o ti wẹ̀ nyin mọ́ kuro ninu aiṣedẽde nyin gbogbo, emi o mu ki a tun gbe ilu, a o si kọ́ ibi ahoro wọnni.

34. Ilẹ ahoro li a o si ro, ti o ti di ahoro li oju gbogbo awọn ti o ti kọja.

35. Nwọn o si wipe, Ilẹ yi ti o ti di ahoro ti dabi ọgbà Edeni; ati ilu ti o tú, ti o di ahoro, ti o si parun, di ilu olodi, o si ni olugbe.

36. Nigbana ni awọn keferi iyokù yika nyin yio mọ̀ pe emi Oluwa ti kọ́ ilu ti o parun, emi si ti gbìn eyiti o ti di ahoro: emi Oluwa ti sọ ọ, emi o si ṣe e.

Ka pipe ipin Esek 36