Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 33:26-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Ẹnyin gbẹkẹle idà nyin, ẹ ṣe irira, olukuluku nyin bà obinrin aladugbò rẹ̀ jẹ́: ẹnyin o ha ni ilẹ na?

27. Iwọ wi bayi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Bi emi ti wà, nitõtọ, awọn ti o wà ninu ahoro na yio ti ipa idà ṣubu, ẹniti o si wà ni gbangba oko li emi o si fi fun ẹranko lati pajẹ, awọn ti o si wà ninu odi ati ninu ihò okuta yio ti ipa ajakalẹ-àrun kú.

28. Nitoriti emi o sọ ilẹ na di ahoro patapata, ọ̀ṣọ nla agbara rẹ̀ kì yio si mọ, awọn oke Israeli yio si di ahoro, ti ẹnikan kì yio le là a kọja.

29. Nigbana ni nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo ba ti sọ ilẹ na di ahoro patapata, nitori gbogbo irira ti nwọn ti ṣe.

30. Iwọ ọmọ enia, sibẹ awọn ọmọ enia rẹ nsọ̀rọ si ọ lẹba ogiri ati lẹba ilẹkun ile, ẹnikini si sọ fun ẹnikeji, olukuluku fun arakunrin rẹ̀ wipe, Wá, emi bẹ̀ ọ si gbọ́ ọ̀rọ ti o ti ọdọ Oluwa jade wá.

31. Nwọn si tọ̀ ọ wá, bi enia ti iwá, nwọn si joko niwaju rẹ bi enia mi, nwọn si gbọ́ ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn nwọn kì yio ṣe wọn: nitori ẹnu wọn ni nwọn fi nfi ifẹ pupọ hàn, ṣugbọn ọkàn wọn tẹ̀le ojukokoro wọn.

32. Si kiyesi i, iwọ jẹ orin ti o dùn pupọ fun wọn, ti ẹnikan ti o ni ohùn daradara, ti o si le fún ohun-elò orin daradara: nitori nwọn gbọ́ ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn nwọn kò ṣe wọn.

33. Ati nigbati eyi bá ṣẹ, (kiyesi i, yio de,) nigbana ni nwọn o mọ̀ pe wolĩ kan ti wà lãrin wọn.

Ka pipe ipin Esek 33