Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 33:24-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Ọmọ enia, awọn ti ngbe ahoro ile Israeli wọnni sọ, wipe, Abrahamu jẹ ẹnikan, on si jogun ilẹ na: ṣugbọn awa pọ̀, a fi ilẹ na fun wa ni ini.

25. Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, ẹnyin njẹ ẹ̀jẹ mọ ẹran, ẹ si gbe oju nyin soke si awọn oriṣa nyin, ẹ si ta ẹjẹ silẹ, ẹnyin o ha ni ilẹ na?

26. Ẹnyin gbẹkẹle idà nyin, ẹ ṣe irira, olukuluku nyin bà obinrin aladugbò rẹ̀ jẹ́: ẹnyin o ha ni ilẹ na?

27. Iwọ wi bayi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Bi emi ti wà, nitõtọ, awọn ti o wà ninu ahoro na yio ti ipa idà ṣubu, ẹniti o si wà ni gbangba oko li emi o si fi fun ẹranko lati pajẹ, awọn ti o si wà ninu odi ati ninu ihò okuta yio ti ipa ajakalẹ-àrun kú.

28. Nitoriti emi o sọ ilẹ na di ahoro patapata, ọ̀ṣọ nla agbara rẹ̀ kì yio si mọ, awọn oke Israeli yio si di ahoro, ti ẹnikan kì yio le là a kọja.

29. Nigbana ni nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo ba ti sọ ilẹ na di ahoro patapata, nitori gbogbo irira ti nwọn ti ṣe.

30. Iwọ ọmọ enia, sibẹ awọn ọmọ enia rẹ nsọ̀rọ si ọ lẹba ogiri ati lẹba ilẹkun ile, ẹnikini si sọ fun ẹnikeji, olukuluku fun arakunrin rẹ̀ wipe, Wá, emi bẹ̀ ọ si gbọ́ ọ̀rọ ti o ti ọdọ Oluwa jade wá.

Ka pipe ipin Esek 33