Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 30:10-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o si ṣe ki ọ̀pọlọpọ enia Egipti ki o ti ipa ọwọ́ Nebukaddressari ọba Babiloni dínkù.

11. On ati enia rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ẹ̀ru awọn orilẹ-ède, li a o mu wá pa ilẹ na run: nwọn o si fà idà wọn yọ si Egipti, nwọn o si fi awọn ti a pa kún ilẹ na.

12. Emi o mu gbogbo odò wọn gbẹ, emi o si tà ilẹ na si ọwọ́ awọn enia buburu; emi o si ti ipa ọwọ́ awọn alejo sọ ilẹ wọn di ahoro, ati ẹkún rẹ̀: Emi Oluwa li o ti sọ ọ.

13. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o pa awọn oriṣa run pẹlu, emi o si jẹ ki ere wọn tán ni Nofi; kì yio si si ọmọ alade kan ni ilẹ Egipti mọ́: emi o si fi ẹ̀ru si ilẹ Egipti.

14. Emi o si sọ Patrosi di ahoro, emi o si gbe iná kalẹ ni Soani, emi o si mu idajọ ṣẹ ni No.

15. Emi o si dà irúnu mi si ori Sini, agbara Egipti; emi o si ké ọ̀pọlọpọ enia No kuro.

16. Emi o si gbe iná kalẹ ni Egipti, Sini yio ni irora nla, a o si fà No ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, Nofi yio si ni ipọnju lojojumọ.

17. Awọn ọdọmọkunrin Afeni ati Pibeseti yio ti ipa idà ṣubu: ati awọn wọnyi yio lọ si igbèkun.

18. Ọjọ yio si ṣõkun ni Tehafnehesi, nigbati emi bá dá àjaga ọrùn Egipti nibẹ: ọṣọ́ agbara rẹ̀ yio tán ninu rẹ̀: bi o ṣe tirẹ̀ ni, ikũkũ yio bò on, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin yio lọ si igbèkun.

19. Bayi li emi o mu idajọ ṣẹ ni Egipti: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

20. O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣù kini, li ọjọ keje oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,

21. Ọmọ enia, emi ti ṣẹ apá Farao ọba Egipti; si kiyesi i, a kì yio dì i ki o ba le san, bẹ̃ni a kì yio fi igi si i lati dì i ki o ba lagbara lati di idà mu.

22. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; kiyesi i, emi dojukọ Farao ọba Egipti, emi o si ṣẹ́ apá rẹ̀, eyi ti o le, ati eyiti o ṣẹ́; emi o si jẹ ki idà bọ́ kuro li ọwọ́ rẹ̀.

23. Emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin awọn orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin ilẹ.

24. Emi o si mu apá ọba Babiloni le, emi o si fi idà mi si ọwọ́ rẹ̀: ṣugbọn emi o ṣẹ́ apá Farao, yio si ma kerora niwaju rẹ bi ikérora ọkunrin ti a ṣá li aṣápa.

Ka pipe ipin Esek 30