Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 30:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,

2. Ọmọ enia, sọtẹlẹ ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹ wu, Egbé fun ọjọ na!

3. Nitori ọjọ na sunmọ tosí, ani ọjọ Oluwa sunmọ tosi, ọjọ ikũkũ ni; yio jẹ akoko ti awọn keferi.

4. Idà yio si wá sori Egipti, irora nla yio wà ni Etiopia, nigbati awọn ti a pa yio ṣubu ni Egipti, nwọn o si mu ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ lọ kuro, ipilẹ rẹ̀ yio si wó lulẹ.

5. Etiopia, ati Libia, ati Lidia, ati gbogbo awọn olùranlọ́wọ, ati Kubu, ati awọn enia ilẹ na ti o mulẹ yio ti ipa idà ṣubu pẹlu wọn.

6. Bayi li Oluwa wi; Awọn pẹlu ti nwọn gbe Egipti ró yio ṣubu; ati igberaga agbara rẹ̀ yio sọkalẹ: lati Migdoli lọ de Siene ni nwọn o ti ipà idà ṣubu ninu rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.

7. Nwọn o si di ahoro li ãrin awọn ilẹ ti o di ahoro, ilu rẹ̀ yio si wà li àrin awọn ilu ti o di ahoro.

8. Nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo bá gbe iná kalẹ ni Egipti, ti gbogbo awọn olùranlọ́wọ rẹ̀ bá parun.

9. Li ọjọ na ni onṣẹ yio lọ lati ọdọ mi ninu ọkọ̀, lati dẹ̀ruba Etiopia ti o wà li alafia, irora yio wá sori wọn gẹgẹ bi li ọjọ Egipti: kiyesi i, o de.

10. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o si ṣe ki ọ̀pọlọpọ enia Egipti ki o ti ipa ọwọ́ Nebukaddressari ọba Babiloni dínkù.

11. On ati enia rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ẹ̀ru awọn orilẹ-ède, li a o mu wá pa ilẹ na run: nwọn o si fà idà wọn yọ si Egipti, nwọn o si fi awọn ti a pa kún ilẹ na.

Ka pipe ipin Esek 30