Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 3:15-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Nigbana ni mo tọ̀ awọn ti igbekùn ti Telabibi lọ, ti nwọn ngbe ẹba odò Kebari, mo si joko nibiti nwọn joko, ẹnu si yà mi bi mo ti wà lãrin wọn ni ijọ meje.

16. O si di igbati o ṣe li opin ijọ meje, ọ̀rọ Oluwa wá sọdọ mi, wipe:

17. Ọmọ enia, mo ti fi iwọ ṣe oluṣọ́ fun ile Israeli, nitorina gbọ́ ọ̀rọ li ẹnu mi, si kilọ fun wọn lati ọdọ mi wá.

18. Nigbati emi wi fun enia buburu pe, Iwọ o kú nitõtọ; ti iwọ kò si kilọ̀ fun u, ti iwọ kò sọ̀rọ lati kilọ fun enia buburu, lati kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, lati gba ẹmi rẹ̀ là; enia buburu na yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀; ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ.

19. Ṣugbọn bi iwọ ba kilọ̀ fun enia buburu, ti kò si kuro ninu buburu rẹ̀, ti ko yipada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ṣugbọn ọrun rẹ mọ́.

20. Ẹ̀wẹ, nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si da ẹ̀ṣẹ, ti mo si fi ohun idigbolu siwaju rẹ, yio kú; nitoriti iwọ kò kilọ fun u, yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, a ki yio ranti ododo rẹ̀ ti o ti ṣe; ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ.

21. Ṣugbọn bi iwọ ba kilọ fun olododo, ki olododo ki o má dẹ̀ṣẹ, ti on kò si ṣẹ̀, yio yè nitotọ, nitori ti a kilọ fun u, ọrùn rẹ si mọ́.

22. Ọwọ́ Oluwa si wà lara mi nibẹ; o si wi fun mi pe, Dide, lọ si pẹtẹlẹ, emi o si ba ọ sọ̀rọ nibẹ.

23. Mo si dide, mo si lọ si pẹtẹlẹ, si kiyesi i ogo Oluwa duro nibẹ, bi ogo ti mo ri lẹba odò Kebari: mo si doju mi bolẹ.

24. Ẹmi si wọ̀ inu mi lọ, o si gbe mi duro li ẹsẹ mi, o si ba mi sọ̀rọ, o si sọ fun mi pe, Lọ, há ara rẹ mọ ile rẹ.

25. Ṣugbọn iwọ, ọmọ enia, kiyesi i, nwọn o si fi idè le ọ, nwọn o si fi dè ọ, iwọ ki yio si jade larin wọn.

26. Emi o si mu ahọn rẹ lẹ mọ oke ẹnu rẹ, iwọ o si yadi, iwọ ki yio jẹ abaniwi si wọn; nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn.

27. Ṣugbọn nigbati mo ba bá ọ sọ̀rọ, emi o ya ẹnu rẹ, iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹniti o gbọ́, jẹ ki o gbọ́; ẹniti o kọ̀, jẹ ki o kọ̀ nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn.

Ka pipe ipin Esek 3