Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 24:7-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nitori ẹjẹ rẹ̀ wà lãrin rẹ̀, o gbé e kà ori apata kan, kò tú u dà sori ilẹ, lati fi erupẹ bò o.

8. Ki o ba lè jẹ ki irúnu ki o de, lati gbẹsan; mo ti gbe ẹjẹ rẹ̀ kà ori apata kan, ki a má ba le bò o.

9. Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Egbe ni fun ilu ẹlẹjẹ na! Emi o tilẹ jẹ ki òkiti iná na tobi.

10. Ko igi jọ si i, ko iná jọ, jo ẹran na, fi turari dùn u; si jẹ ki egungun na jona.

11. Si gbe e kà ori ẹyín iná na lasan, ki idẹ rẹ̀ le gbona, ki o le pọ́n, ati ki ẽri rẹ̀ le di yiyọ́ ninu rẹ̀, ki ifõfo rẹ̀ le run.

12. On ti fi eke dá ara rẹ̀ lagara, ifõfo nla rẹ̀ kò si jade kuro lara rẹ̀ ifõfo rẹ̀ yio wà ninu iná.

13. Ninu ẽri rẹ̀ ni iwà ifẹkufẹ wà: nitori mo ti wẹ̀ ọ, iwọ kò si mọ́, a kì yio si tun wẹ̀ ọ kuro ninu ẽri rẹ mọ, titi emi o fi jẹ ki irúnu mi ba le ọ lori.

14. Emi Oluwa li o ti sọ ọ, yio si ṣẹ, emi o si ṣe e: emi kì yio pada sẹhìn, bẹ̃ni emi kì yio dasi, bẹ̃ni emi kì yio ronupiwada; gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, ati gẹgẹ bi iṣe rẹ ni nwọn o da ọ lẹjọ, li Oluwa Ọlọrun wi.

15. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

16. Ọmọ enia, kiye si i, mo mu ifẹ oju rẹ kuro lọdọ rẹ, nipa lilù kan: ṣugbọn iwọ kò gbọdọ gbãwẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sọkun, bẹ̃ni omije rẹ kò gbọdọ ṣan silẹ.

17. Máṣe sọkun, máṣe gbãwẹ fun okú, wé lawàni sori rẹ, si bọ̀ bata rẹ si ẹsẹ rẹ, máṣe bò ète rẹ, máṣe jẹ onjẹ enia.

18. Bẹ̃ni mo sọ fun awọn enia li owurọ: li aṣálẹ obinrin mi si kú, mo si ṣe li owurọ bi a ti pá a li aṣẹ fun mi.

19. Awọn enia si sọ fun mi wipe, Iwọ kì yio ha sọ fun wa ohun ti nkan wọnyi jasi fun wa, ti iwọ ṣe bayi?

20. Mo si da wọn lohùn pe, Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe,

Ka pipe ipin Esek 24