Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 22:23-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

24. Ọmọ enia, sọ fun u, Iwọ ni ilẹ ti a kò gbá mọ́, ti a kò si rọ̀jo si i lori lọjọ ibinu.

25. Ìditẹ awọn wolĩ rẹ̀ wà lãrin rẹ̀, bi kiniun ti nke ramuramu ti nṣọdẹ; nwọn ti jẹ ọkàn run, nwọn ti kó ohun iṣura ati ohun iyebiye; nwọn ti sọ ọ̀pọlọpọ di opó fun u lãrin rẹ̀.

26. Awọn alufa rẹ̀ ti rú ofin mi, nwọn si fi sọ ohun mimọ́ mi di àilọwọ: nwọn kò fi ìyatọ sãrin ohun mimọ́ ati àilọwọ, bẹ̃ni nwọn kò fi ìyatọ hàn lãrin ohun aimọ́, ati mimọ́, nwọn si ti fi oju wọn pamọ kuro li ọjọ isimi mi, mo si di ẹmi àilọwọ lãrin wọn.

27. Awọn ọmọ-alade ãrin rẹ̀ dabi kõkò ti nṣọdẹ, lati tàjẹ silẹ, lati pa ọkàn run, lati jère aiṣõtọ.

28. Ati awọn wolĩ rẹ̀ ti fi ẹfun kùn wọn, nwọn nri asan, nwọn si nfọ afọ̀ṣẹ eke si wọn, wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, nigbati o ṣepe Oluwa kò sọ̀rọ.

29. Awọn enia ilẹ na, ti lo ìwa-ininilara, nwọn si ja olè, nwọn si ti bi awọn talaka ati alaini ninu: nitõtọ, nwọn ti ni alejò lara lainidi.

30. Emi si wá ẹnikan lãrin wọn, ti ibá tun odi na mọ, ti ibá duro ni ibiti o ya na niwaju mi fun ilẹ na, ki emi má bà parun: ṣugbọn emi kò ri ẹnikan.

31. Nitorina ni mo ṣe dà ibinu mi si wọn lori; mo ti fi iná ibinu mi run wọn: mo si ti fi ọ̀na wọn gbẹsan lori ara wọn, li Oluwa Ọlọrun wi.

Ka pipe ipin Esek 22