Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 20:42-49 Yorùbá Bibeli (YCE)

42. Ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa, nigbati emi o mu nyin de ilẹ Israeli, si ilẹ niti eyiti o gbe ọwọ́ mi soke lati fi fun awọn baba nyin.

43. Nibẹ li ẹnyin o ranti ọ̀na nyin, ati gbogbo iṣe nyin, ninu eyiti a ti bà nyin jẹ; ẹ o si sú ara nyin loju ara nyin nitori gbogbo buburu ti ẹnyin ti ṣe.

44. Ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa, nigbati emi ti ṣiṣẹ pẹlu nyin nitori orukọ mi, ki iṣe gẹgẹ bi ọ̀na buburu nyin, tabi gẹgẹ bi iṣe bibajẹ nyin, ẹnyin ile Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi.

45. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

46. Ọmọ enia, kọju rẹ siha gusù, si sọ ọ̀rọ rẹ siha gusù, si sọtẹlẹ si igbó oko gusù;

47. Si wi fun igbó gusù pe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa; bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o da iná kan ninu rẹ, yio si jo olukuluku igi tutù ninu rẹ, ati olukuluku igi gbigbẹ: jijo ọwọ́ iná na ni a kì yio pa, ati gbogbo oju lati gusu de ariwa ni a o sun ninu rẹ̀.

48. Gbogbo ẹran-ara ni yio si ri i pe emi Oluwa li o ti da a, a kì yio pa a.

49. Nigbana ni mo wipe, A! Oluwa Ọlọrun, nwọn wi niti emi pe, Owe ki o npa yi?

Ka pipe ipin Esek 20