Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 19:6-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. On si lọ soke lọ sodo lãrin awọn kiniun, o di ọmọ kiniun, o si kọ́ lati ṣọdẹ, o si pa enia jẹ.

7. On si mọ̀ awọn opo wọn, o si sọ ilu-nla wọn di ahoro; ilẹ na di ahoro, ati ẹkún rẹ̀, pẹlu nipa ariwo kike ramuramu rẹ̀.

8. Nigbana ni awọn orilẹ-ède kó tì i nihà gbogbo lati ìgberiko wá, nwọn si na awọ̀n wọn le e lori: a mu u ninu iho wọn.

9. Nwọn si fi i sinu ẹṣọ́ ninu ẹ̀wọn, nwọn si mu u wá sọdọ ọba Babiloni: nwọn mu u lọ sinu ilu olodi, ki a má ba gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ lori oke Israeli.

10. Iyá rẹ dabi àjara kan ninu ẹjẹ rẹ, ti a gbìn si eti odò, on kún fun eso, o si kún fun ẹka nitori ọ̀pọlọpọ odò.

11. O si ni ọpá ti o le fun ọpá-ade awọn ti o jẹ oye; giga rẹ̀ li a gbega lãrin ẹka gigun, o si farahàn ninu giga rẹ̀ pẹlu ọ̀pọlọpọ ẹka rẹ̀.

12. Ṣugbọn a fã a tu ni irúnu, a wọ ọ lulẹ, ẹfũfu ila-õrun si gbe eso rẹ̀, ọpá lile rẹ̀ ti ṣẹ, o si rọ; iná jo o run.

13. Nisisiyi a si gbìn i si aginju, ni ilẹ gbigbẹ ati ilẹ ongbẹ.

Ka pipe ipin Esek 19