orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 19 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PẸLUPẸLU iwọ pohùn-rére ẹkun fun awọn ọmọ-alade Israeli,

2. Si wipe, Kini iyá rẹ? Abo kiniun: o dubulẹ lãrin kiniun, o bọ́ awọn ọmọ rẹ lãrin ọmọ kiniun.

3. O si tọ́ ọkan ninu ọmọ rẹ̀ dàgba: o di ọmọ kiniun, o si kọ́ ati ṣọdẹ; o pa enia jẹ.

4. Awọn orilẹ-ède pẹlu gburo rẹ̀: a mu u ninu iho wọn, nwọn si fi ẹ̀wọn mu u lọ si ilẹ Egipti.

5. Nigbati o si ri pe on si duro, ti ireti rẹ̀ si sọnu, nigbana ni o mu omiran ninu ọmọ rẹ̀, o si sọ ọ di ọmọ kiniun.

6. On si lọ soke lọ sodo lãrin awọn kiniun, o di ọmọ kiniun, o si kọ́ lati ṣọdẹ, o si pa enia jẹ.

7. On si mọ̀ awọn opo wọn, o si sọ ilu-nla wọn di ahoro; ilẹ na di ahoro, ati ẹkún rẹ̀, pẹlu nipa ariwo kike ramuramu rẹ̀.

8. Nigbana ni awọn orilẹ-ède kó tì i nihà gbogbo lati ìgberiko wá, nwọn si na awọ̀n wọn le e lori: a mu u ninu iho wọn.

9. Nwọn si fi i sinu ẹṣọ́ ninu ẹ̀wọn, nwọn si mu u wá sọdọ ọba Babiloni: nwọn mu u lọ sinu ilu olodi, ki a má ba gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ lori oke Israeli.

10. Iyá rẹ dabi àjara kan ninu ẹjẹ rẹ, ti a gbìn si eti odò, on kún fun eso, o si kún fun ẹka nitori ọ̀pọlọpọ odò.

11. O si ni ọpá ti o le fun ọpá-ade awọn ti o jẹ oye; giga rẹ̀ li a gbega lãrin ẹka gigun, o si farahàn ninu giga rẹ̀ pẹlu ọ̀pọlọpọ ẹka rẹ̀.

12. Ṣugbọn a fã a tu ni irúnu, a wọ ọ lulẹ, ẹfũfu ila-õrun si gbe eso rẹ̀, ọpá lile rẹ̀ ti ṣẹ, o si rọ; iná jo o run.

13. Nisisiyi a si gbìn i si aginju, ni ilẹ gbigbẹ ati ilẹ ongbẹ.

14. Iná si jade lati inu ọpá kan ninu ẹka rẹ̀, ti o ti jo eso rẹ̀ run, tobẹ̃ ti kò fi ni ẹka ti o le lati ṣe ọpa lati joye. Eyi ni ohùnrére ẹkun, yio si jẹ ohùn-rére ẹkun.